BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Top Stories
Ọlọ́pàá ti ránsẹ́ pe Naira Marley, Sam Larry àti àwọn tí ọ̀rọ̀ ikú Mohbad kàn- Iyabo Ojo
Ṣaaju ni kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Eko gbe igbimọ ẹlẹni mẹtala kan dide lati tọ pinpin ohun to ṣe okunfa iku Mohbad.
Àlàyé rèé lórí bí ilé ẹjọ́ ṣe fún Oluwo Nla Tede ní béèlì tó sì sún ìgbẹ́jọ́ Tani Olohun síwíajú
Adajọ sun igbẹjọ si ọjọ Aje, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii.
Ìjọba kéde kónílé gbélé ni Kano lẹ́yìn ìdájọ́ Tribunal
Ẹwẹ, ẹgbẹ NNPP to sọ pe oun ko faramọ idajọ naa, ati pe oun maa to pe ẹjọ kotẹmilọrun.
Irọ̀ ni pé Dókítà ṣe iṣẹ́ fún wákàtí 72- LUTH
Saaju ni awọn igbimọ Dokita ti ẹka LUTH, ninu atẹjade kan ti wọn fi lede pe Dr Umoh jade laye nitori o wa lẹnu isẹ fun ọjọ mẹta gbako.
Láti gbógun ti ààrùn, àwọn ọ̀dọ́ kó arawọn jọ láti ṣe ìmọ́tótó
Dwanyne Nyambo, oludasilẹ ‘vibrant keeps it clean’ ni ipiinu oun ni lati ṣe amojuto gbogbo ọga ni Malawi.
Akeredolu ṣèlérí láti fi ìyá òfin jẹ alága APC tó lú Kọmísọ́nnà
Gomina kede ọrọ ninu atẹjade ti Kọmisọna fun ọrọ iroyin, Bamidele Ademola Olateju, Akeredolu ni igbesẹ Awolumate ni o da bi pe eeyan si ọwọ lu ijọba, ti ijọba rẹ ko si le fi aye gba irufẹ iwa bẹ.
Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ondo kọ̀wé sí igbákejì gómìnà kó wá wí tẹnu rẹ̀ lórí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́
Adari ọmọ ile to pọ ju lọ, Oluwole Ogunmolasuyi, lo gbe aba naa kalẹ niwaju awọn akẹgbẹ rẹ, ti Tope Agbulu, to n ṣoju ẹkun iwọ-oorun-guusu Akoko keji, si kin aba naa lẹyin.
‘’Olóògbé Taiwo Akinkunmi tó ya àsìá Nàìjíríà ṣe gudugudu méje láti mú ìsọ̀kan bá orílẹ̀èdè wa’’
Olùdarí àjọ ètò ìlánilọ́yẹ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ọ̀mọ̀wé Garba Abari ni ipa pàtàkì tí olóògbé Taiwo Akinkunmi kó nípa ìsọ̀kan àti àlàáfíà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kò ṣeé fọwọ́rọ́ sẹ́yìn.
Àwọn ohun tí ojú mi rí lábẹ́ Bayowa kò kéré, mo ta ilé, ta dúkìá - Busola Oke Eleyele
Nínú fídíò kan tí Busola Oke tó ṣe lórí TikTok rẹ̀ ní ojú òun rí tó lọ́wọ́ Bayowa nítorí òun kò rí àǹfàní kankan jẹ lórí àwọn orin tí òun ṣe lábẹ́ ilé iṣẹ́ rẹ̀.
Ìròyìn Àkàgbádùn
Ọmọ tí ìfun rẹ̀ di àwátì nílé ìwòsàn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ jáde láyé
Debola Akin-Bright ti ń gba ìtọ́jú, tó sì ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ abẹ níbi tí wọ́n ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìfun rẹ̀ kò sí nínú rẹ̀ mọ́.
‘’Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń sọ fún mi pé mi ò lè lówó mọ́ láyé lẹ́yìn tí mo dá N15m èrò tí mo gbé padà’’
Ẹbi oniṣowo orilẹede Chad to ni owo naa, Musa Hassan dupẹ lọwọ Auwal lori bi o ti da owo ọhun pada.
A wọ́gilé gbogbo ipò Yoruba tí Obasanjo jẹ - YCW
Oluwo ti ile Iwo, Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi, tiẹ kepe Obasanjo lati tọrọ aforijin tori pe o wọ awọn ọba alaye nlẹ pẹlu ọrọ to sọ.
Ó ṣéese kí àwọn tó ń lo 'X' bẹ̀rẹ̀ sí ní san owó láìpẹ̀- Elon Musk
O sọ eleyi lasiko to n ba Olotu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu sọrọ. O ni si san owo nikan ni ọna abayọ lati gbe ogun ti awọn ipenija ayelujara naa.
Kò fẹ̀ẹ́ sí ọ̀dọ́ Ṣagamu tí kìí ṣé omọ ẹgbẹ́ òkùnkùn-Alukoro Ọlọ́pàá Adejobi
Lemọlemọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lagbagbe Shagamu tí wá fẹ kọja afarada lẹnu ọjọ mẹta yi.
Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ níbi ìfẹ̀hónúhàn l'Abeokuta lórí ikú tó pa Mohbad
Ko din ni ẹgbẹrun meji awọn ọdọ ti wọn korajọ lati fẹhonuhan lonii, ti awọn oṣiṣẹ agbofinro si wa nibẹ lati daabobo awọn eeyan.
Àwọn Iléeṣẹ́ Rédíò kan ti fi òfin de lílo orin Naira Marley
L'ọjọ Aje ni awọn oludasilẹ ileeṣe redio ni ẹkun iwọorun guusu fi aṣẹ lelẹ ti wọn si kede wi pe gbogbo orin Naira Marley ati awọn isọgbe rẹ ti di eewọ lori ikanni redio wọn.
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú Xenophobic attack lorílẹ̀-èdè South Africa?
“Lotitọ mo korira awọn ajoji . O wumi ki wọn ko gbogbo ẹru wọn kuro lorilẹede wa" BBC Africa Eye fi oju kan da si isẹlẹ bi awọn ọmọ ẹgbẹ ikọ naa ṣe n sisẹ.
Ipò Aláàfin kì í ṣe fún títà- Seyi Makinde
Makinde ti o sọ ọrọ naa nibi iṣide opopona tuntun Ọyọ-Iṣẹyin lọjọ Ẹti fi kun ọrọ rẹ pe ipo Alaafin ko si fun karakata.
Lójú mi ni àwọn agbébọn ti ṣekúpa Bàbá mi - Teni Apata
O ni ọpọlọpọ nnkan ti isẹlẹ ti fa si oun lara, to si ṣe akoba nla fun igbe aye rẹ.
Ọmọ ọdún méjì ni mí nígbà tí ìyà mí gbé mi sílẹ̀ - Bimbo Ademoye
Ademoye sọ eleyi ninu ifọrọwerọ pẹlu Hauwa Magaji ni ibaṣepọ oun pẹlu iya ko kuna to gẹgẹ bi ti iya si ọmọ.
N kò wá ọkọ o- Motunde Sogunle pariwo síta
Motunde sọ eleyi ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Sunday Scoop nipe ipa ti oun ko ninu ere ori ayelujara ni ọpọ ti gba si otitọ pe bi oun ṣe n gbe igbe aye rẹ niyẹn.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Móríwú
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Kíní ọ̀nà àbáyọ sí awuyewuye ìgbà gbogbo láàrin Gómìnà àti igbákejì wọn ní Nàìjíríà?
Ija yi a maa le debi pe wọn a sí maa yọ igbakeji Gomina kuro nipo.
Sáyẹ́ǹsì àbaàdì: Lílo AI láti fi kọ́ àwọn ọmọdé ní ìmọ̀ òfégè
Ikọ̀ ìròyìn BBC ṣe àwàrí àwọn ojú òpó náà tó lé ní àádọ́ta tí wọ́n ń lo èdè tó lé ní ogún láti máa fi pín àwọn ìròyìn òfégè nípa sáyẹ́ǹsì, ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ìmọ̀ ìṣìrọ.
Atiku àti Obi gbé Tinubu lọ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ pé kò wọlé ìbò ààrẹ
Ni ọkọ kẹfa oṣu Kẹsan an ni ile ẹjọ kotẹmilọrun gbe idajọ rẹ kalẹ elyii to fi fontẹ Tinubu gẹgẹ bi oludije to wọle ibo aarẹ Naijiria ni ọjó kẹẹdọgbọn oṣu keji ọdun 2023 yii.
Wo Jamila àti Ayodele tí Tinubu yàn sípò mínísítà ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́
Aarẹ Tinubu rọ awọn mejeeji lati ṣiṣẹ takun takun gẹgẹ bi ọdọ ni ipo ti oun yan wọn si.
Olùkọ kàn réè tó pàdánù akẹ́kọ̀ọ́ rẹ 32 nínú ìṣẹlẹ ilẹ́ riri
Nesreen Abu ElFadel, olùkọ ede larubawa ati Faransé ni Marrakech lo n sọ nípa iriri rẹ lọjọ to sare lọ sí abúlé rẹ Adassel tó wa lagbegbe ori oke nla Atlas.
O lé ní ẹgbẹ̀rún kan ìgbéyàwó tó forí ṣánpọ́n ní Kano, kí l'ohun tó wà nídìí ọ̀rọ̀ yìí?
Lọpọ igba awọn igbeyawo wọnyi ki pẹ pupọ ki wọn to tuka ti eleyi si n kọ awọn alaṣẹ ati araalu lominu ni Kano.
Wo aṣọ Diana Olorì tẹ́lẹ̀ rí Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Charles tí ẹnìkan rà ní N878m
Lady Diana's clothes: Wo aṣọ Diana Olorì tẹ́lẹ̀ rí Ọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì Charles tí ẹnìkan rà ní N878m
Àwọn òbí banújẹ́ báwọn ọmọ tó ti kú ṣe ń sọ̀rọ̀ bíi alàyè lórí TikTok láti sọ ohun tó pa wọ́n
Baroness Beeban Kidron, to jẹ ọkan lara awọn aṣofin ilẹ Gẹẹsi sọ pe nnkan ibanujẹ ni ki obi maa wo fidio ọmọ rẹ to ti ku, ko maa sọrọ nipa bi wọn ṣe pa a.
Wo àkóbá tí àdínkù súnkẹrẹ fàkẹrẹ ṣe nílùú Eko lẹ́yìn yíyọ owó ìrànwọ́ epo
Awọn eeyan kan ti ṣe ifẹhonuhan kaakiri lori bi ilu ṣe le kankan lẹyin ti ijọba owo iranwọ ori epo, amọ, ifẹhonuhan naa ko fẹsẹ mulẹ.