Ipaniyan Benue: Buhari sepade pẹlu awọn t'ọrọ kan

Ninu alaye ọrọ ti wọn fi lede lori itọna twitter lẹyin ipade naa, Aarẹ Orilẹ ede Naijiria, Muhammadu Buhari seleri lati se imusẹ ileri eto aabo to muna-doko fun gbogbo ọmọ orilẹ-ede Naijiria.

O tẹsiwaju wipe ajọ ọlọpa, ile isẹ ologun ati ajọ ọtẹlẹmuyẹ ti n sisẹ takuntakun lati mu idaabo bo ipinlẹ Benue ati lati fi oju awọn apaniyan wina ofin.

Image copyright MUHAMMADU BUHARI
Àkọlé àwòrán Aarẹ Orilẹ ede Naijiria, Muhammadu Buhari seleri lati se imusẹ ileri eto aabo to muna-doko fun gbogbo ọmọ orilẹ-ede

A o ranti wipe awọn eniyan bii mẹtalelaadorin niwọn padanu ẹmin wọn sọwọ ija ti o waye laarin awọn darandaran ati awọn agbẹ nilu Makurdi ti o jẹ olu ilu ipinle Benue.

Image copyright MUHAMMADU BUHARI/TWITTER
Àkọlé àwòrán Muhammadu Buhari se ipade pelu awon eniyan lati Benue

Related Topics