Ọmọ igboro to di ayaworan pataki lawujọ

Mario Macilau Image copyright MARIO MACILAU/WATER AID
Àkọlé àwòrán Mario Macilau

Ọmọ ọdun metalelogun kan, Mario Macilau lọdun 2007 fi ẹrọ ibanisọrọ alagbeka iya rẹ se pasiparọpẹlu ẹro iyaworan Nikon. Aworan yiya ko jẹ tuntun sii nitori lati igba ewe rẹ ni o ti'n ya aworan ni ilu rẹ, Maputo tii se olu ilu Mozambique.

Image copyright WATER AID/MARIO MACILAU
Àkọlé àwòrán Ọkan lara aworan ti Mario Macilau ya

Bi o se nya aworan awọn ọmọ igboro ti won ngbe inu awọn ile ti ko ri eeyan gbe inu wọn, bẹẹ ni a maa ya aworan awọn osisẹ ile ise to npo simenti.

Sugbọn bayi,o ti kọ oju aworan yiya rẹ si akori ọrọ to ni se pẹlu omi. Awọn aworan wọnyi ti o ya ni opin ọdun 2017 pẹlu ajọsepo ajọ alaanu to npese iranwọ omi (Water Aid) fun akojọpọ aworan kan ti wọn pe ni 'Untapped Appeal' eleyi ti afihan rẹ yio waye titi di opin osu kini ọdun yii.

Laarin ọdun mẹta to mbọ, Macilau yio se afihan ipa ribiribi ti ipese omi abumu ati ile igbọnse nko ni igbesi aye awọn ara adugbo ẹkun Cuamba ni ilu Mozambique.

Image copyright WATER AID/MACILAU
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọde ni agbegbe ibi ti ipenija omi wa nilẹ Mozambique
Image copyright WATER AID/MACILAU
Àkọlé àwòrán Josefina a maa fi ori ru omi lọ ọna jinjin

Josefina ti aworan rẹ wa loke ati Eudicia ti won je ọmọ ọdun mejila a maa padanu ile ẹko bi ẹmẹẹrin lọse ki wọn ba le lọ pọn omi.

Wọn ma nrin lọ si Rio Naranja nibi ti omi isẹleru kan wa eyi ti o nsan jade latara odo Muassi tii se orisun omi kan soso ti awon ara abule Muassi npọn.

Omi adagun ti o pọ́n lomi naa ti awọn ọmọbirin ọun ma npọn.

Ajọ alaanu to npese iranwọ omi sọ wipe ọkan ninu awọn ọmọ mẹsan lagbaye ni ko ni anfaani lati ri omi t'o see mu lagbegbe wọn ati pe ọkan ninu eeyan mẹta ni ko ni ile igbọnsẹ.

Won tun ni lojojumo o fẹrẹẹ to omo ẹgbẹrin ti ọjọ ori wọn ko tii to ọdun marun ti wọn ma nse alaisi lataari aarun igbẹ gbuuru ti omi idọti ati ayika ti ko mo ma nse okunfa rẹ.

Image copyright WATER AID/MACILAU
Àkọlé àwòrán Omi adagun Muassi tii se orisun omi kan soso ti awọn ara abule Muassi npọn
Image copyright WATER AID/MACILAU
Àkọlé àwòrán Ori ni awọn omo obirin to npon omi ọhun fi nru omi lọ ọna jinjin
Image copyright WATER AID/MACILAU
Àkọlé àwòrán Omi adagun ti awọn ara abule Muassi npọn

Ni asiko ojo, odo Lurio kii see mu mọ nitori idọti ati ẹgbin ti wọn ma nda si inu rẹ

Labule M'mele, nise ni ojo ba ile alamo kan je latari ojo to rọ arọọ'rọda lọdun mẹta sẹyin.

Awọn agbaagba ilu ni nise ni awọn eniyan fi'luu lẹ nitori ipenija omi abuwẹ abumu.

Image copyright WATER AID/MACILAU
Àkọlé àwòrán Ile alamọ t'ojo se ijamba fun
Image copyright WATER AID/MACILAU
Àkọlé àwòrán Aworan agba ilu kan ti Macilau ya
Image copyright WATER AID/MACILAU
Àkọlé àwòrán Elisa Piassone ati Zaida nrin lọ loju ọna to wa ni aarin Mmele ati Kimar nibi ti wọn ngbe agbado lilọ lọ

Ajọ alaanu to npese iranwọ omi (Water Aid) ati Mario Macilau ni wọn ni awọn aworan wọnyii.

Related Topics