Libya: Ọmọ Naijiria mejilelaadoje miran pada sile

ọmọ Naijiria mejilelaadoje pada sile lati orilẹede Libya Image copyright ABIKJE DABIRI/TWITTER
Àkọlé àwòrán ọmọ Naijiria mejilelaadoje pada sile lati orilẹede Libya

Ajọ to n risi eto irinna lati agbegbe kan si ominran lagbaye (IOM) pelu iranwọ ajọ isọkan orillẹede Europe (EU), ti da awon ọmọ Naijiria mejilelaadoje pada sile lati orilẹede Libya, leyin ti Ojilelẹẹdẹgbẹta pada sile lọse to kọja.

Awọn abilekọ, Baale ile ati ọmọde lo wa lara awọn arinrinajo naa.

Ileesẹ akoroyinjọ nilẹ Naijiria (NAN) sọ pe, awọn arinrinajo naa de si papakọ ofurufu Murtala Muhammed ti ilu Eko, ni deede agogo Marun abọ nirọle ana, pelu awọn obinrin abilekọ bii marundinlogoji, baale ile mejidinlaadọrin ati awọn ọmọde mẹsan.

Awọn ajọ to wa fọrọ awọn atipo ki wọn kaabọ.

Aajọ to n risi ọrọ irinajo lorilẹede Naijiria,(NIS) pẹlu ajo to n gbogun ti iwa ifini sowo ẹru lorilẹede Naijiria ati Ajọ papakọ to n sakoso papakọ ofurufu lorilẹede Naijiria ni wọn ki awọn arinriajo naa kabọ sorilẹede yi.

Ọmọ Naijiria toto ẹgberun mefa ati egberin ole mefa(6,806) lo ti pada sile bayi lati orilẹede Libya. Tẹẹ ba gbagbe, Ojilelẹẹdegbẹta ọmọ Naijiria, to jẹ isi kinni awọn ọmọ Naijiria to rinrin ajo lọ silẹ Libya, lo pada de si ilu Port Harcourt lọse to kọja.