APC àti PDP takora wọn lórí Olùsirò owó àgba Ọsun tó fisẹ́ sílẹ̀

Rauf Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Sola Fasure

Àkọlé àwòrán,

Aregbesola yan elòmíràn dípò Oyetola

Ní báyìí tí ìdìbò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun kù sáátá, ọ̀pọ̀ awuyewuye ló gba ilẹ̀ kan nítorí bí Olùsirò owó àgba, Alaba Akintayọ se kúrò lẹ́nu isẹ́.

Nibayii ti eto idibo gomina ipinlẹ Ọsun, ti yoo waye lọjọ kejilelogun osu kẹsan ọdun 2018, ku fẹẹrẹfẹ ko waye, oniruuru awuyewuye lo ti n su yọ, paapa eyi to nii se pẹlu bi olusiro owo agba nipinlẹ naa, Ọgbẹni Alaba Akintayọ se kọwe fipo silẹ.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olusiro owo agba naa ti pe ẹni ọgọ̀ta ọdun losu keje ọdun 2018, to si yẹ ko ti fi isẹ silẹ, sugbọn a gbọ̀ pe ijọba ipinlẹ Ọsun se afikun akoko to yẹ ko lo. Amọ ibeere to wa n daamu ọ̀kan awọn eeyan ni pe o se jẹ pe akoko ti ipalẹmọ feto idibo Ọsun doju ọgbagade, ni Akintayọ sọ̀ pe oun ko sisẹ mọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Adebisi Idikan: Òun ló gba Ìbàdàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà owó orí sísan

Nigba to n tan imọlẹ́ si ibeere yii, Kọmisọna feto iroyin nipinlẹ Ọsun, Ọgbẹni Lanny Baderinwa ni irọ to jinna sootọ ni pe Akintayọ kọwe fi isẹ silẹ laipe ọjọ, to si rọ awọn eeyan lati kẹyin si iru ahesọ ọrọ bii eyi.

"Ko si awo kankan ninu awo ẹwa lori bi olusiro owo agba naa se kọwe silẹ, amọ o se bẹẹ, nitori pe o ti le ni ẹni ọgọta ọdun ni."

Atẹjade ti Baderinwa fi sita, eyi to sisọ loju ọrọ yii ni, Akintayọ ti sisẹ kara fun ijọba ipinlẹ Ọsun, ti isẹ ọba yoo si mọ ifẹyinti rẹ lara.

Bakan naa ni atẹjade ọhun ni, gomina ipinlẹ Ọ́sun, Rauf Arẹgbẹsọla ti ki Alaba Akintayọ ku oriire ifẹyinti rẹ, to si tun gbadura fun pe yoo mọ akoko naa si rere.

Àkọlé àwòrán,

PDP ni ifisẹ silẹ Akintayọ nii se pẹlu owo kan, eyi to le ni biliọnu mẹrindinlogun naira

Sugbọn ẹgbẹ alatako kan nipinlẹ Ọsun, eyiun ẹgbẹ oselu PDP ti n ke tantan pe, ifisẹ silẹ Akintayọ nii se pẹlu owo kan, eyi to le ni biliọnu mẹrindinlogun naira tijọba apapọ yọgbe jade fun ipinlẹ Ọsun gẹgẹ bii owo idapada gbese.

Atẹjade kan ti alaga fẹgbẹ PDP ni ipinlẹ Ọsun, Sọji Adagunodo fisita wa kesi awọn ileesẹ to n gbogun ti iwa ibajẹ, lati dide tanna imọlẹ wọn si ẹsun yii.

PDP tun bu ẹnu atẹ lu ijọba apapọ pe o n fi ọgbọ̀n-ọ̀gbọn pese owona fun ijọba ipinlẹ Ọsun lori eto idibo naa, pẹlu bo se ni oun da owo to le biliọnu mẹrindinlogun naira pada gẹgẹ bii owo to san le lori gbese Paris Club pada.

Arẹgbẹ́sọla yan olori osisẹ tuntun

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọsun Ọgbẹ́ni Rauf Aregbẹsọla ti yan Ọgbẹ́ni Abdulrasak Salinsile gẹ́gẹ́ bí olorí àwọn oṣiṣẹ ní ile ìjọba ìpínlẹ̀ náà.

Ọgbẹ́ni Sola Fasure tó jẹ́ agbẹnusọ lórí ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ fún gómìnà Arẹgbẹ́sọla ló sọ èyí dí mímọ lónì nílú Osogbo.

Fasure sọ pé àwọn ọmọ ìgbìmọ aláṣẹ ìjọba ló fọwọ́ sí i lásìkò ìpádé wọn, o fí kún-un pé wọn ti búra wọlé fún olóri òṣìṣẹ́ túntun náà ní wàràńṣeṣà.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn NAN ṣe sọ ọ, Salinsile ló ń rọ́ pò Alhaji Oyetola Gboyega tó ti di oludije fun ipò gomìnà lábẹ́ àsía ẹgbẹ́ òṣèlú APC níbi ìdìbò tí yóò wáye lọ́jọ́ kejìlélógun oṣù yìí nípìnlẹ̀ Oṣun.

Ìgbìmọ aláṣẹ bákan náà tún fọwọ sí yíyàn Ọgbẹni Tunde Adedeji gẹ́gẹ́ bí alaga àjọ tó ń mójú to ìjọba ìbílẹ̀.

Ikorira, ipaniyan ati ika nsun Naijiria soju ogun-Arẹgbẹsọla

Oríṣun àwòrán, RAUF AREGBESOLA/FACEBOOK

Àkọlé àwòrán,

Gomina ipinlẹ Ọsun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹsọla nlọgun pe ki awọn ọmọ Naijiria sọra

Gomina ipinlẹ Ọsun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹsọla ti nlọgun too pe, ti awọn ọmọ Naijiria ko ba sọra, afaimọ ki wọn ma ti orilẹede yi lọ soju ogun nitori ọrọ ikorira, ipaniyan ati iwa ika ti wọn n hu laibikita.

Ko ni dara ki ina eesi tun jo wa lẹẹkeji.

Gomina Arẹgbẹsọla fikun pe ilẹ Naijiria sorire lati tete jajabọ ninu ogun abẹle akọkọ pẹlu afikun pe eyi lee ma ri bẹẹ mọ fun ilẹ Naijiria to ba tun fi lọ si ogun abẹle ẹlẹẹkeji, nitori oju apa ko lee jọ oju ara mọ.

Ọgbẹni Arẹgbẹsọla keboosi imọran yi sita lasiko ayẹyẹ iranti ọlọdọọdun awọn akọni to ti sun loju ija atawọn to fara gbọgbẹ eyi to waye nilu Osogbo.

Oríṣun àwòrán, RAUF AREGBESOLA/FACEBOOK

Àkọlé àwòrán,

Gomina ipinlẹ Ọsun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹsọla nlọgun pe ki awọn ọmọ Naijiria sọra

O yẹ kawọn ọmọ jawọ ninu iwa ipaniyan, ọrọ ikorira ati iwa ika.

Atẹjade kan ti Amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin, Sọla Fasure fisita ni, lasiko ton sọrọ lori iwa isekupani awọn Fulani, Gomina Arẹgbẹsọla ni o se pataki ki ọmọ orilẹede yi kọọkan sisẹ papọ fun alaafia orilẹede yi nipa tita kete sawọn ohunkohun to ba lee sokunfa ogun ati ọtẹ.

"latipasẹ ijafara, ainironu jinlẹ, imọtaraẹni nikan iwa ika, ati iwa ikorira, o seese ki ilẹ Naijiria tun maa ti ara rẹ sinu ogun abẹle minran, bẹẹ si ni , ogun jẹ okoowo to buru pupọ, o maa ngbọn owo pupọ lọ, o n seku pa ọpọ eeyan, to si tun maa nba ọpọ dukia jẹ, koda, eyi gan kan ẹni yowu ko bori ogun naa."

Alaafia nikan lo lee mu idagbasoke ba ilẹ Naijiria.

Arẹbẹsọla wa sapejuwe iwa alaafia gẹgẹ bii ipilẹ rere fun ọrọ aje ati idagbasoke oselu nitori ko si idagbasoke kankan to lee waye lasiko ogun.