CHAN: Ikọ Eagles de si Tangier loni

Ikọ Super Eagles Image copyright NFF/TWITTER
Àkọlé àwòrán Ikọ Super Eagles

Ikọ ẹgbẹ agbaọọlu Naijiria ti a mọ si CHAN Eagles yi o de si Tangier ni orilẹ ede Morocco loni lati mura silẹ fun idije agbabọọlu adulawọ (CAF) ni orile-ede Rwanda ni asalẹ ọjọ aje.

CHAN Eagles ti wọn gba ọọmi pẹlu ikọ agbabọọlu ti orilẹ ede Cameroon ni ọjọbọ ni Rabat ni igbaradi fun idije agbabọọlu adulawọ (CAF); ti awọn oṣiṣẹ alakoso ikọ ọmọ ẹgbẹ agbaọọlu Naijiria sọ wipe ikọ naa wa ni ipo ti o dara julọ lati lepa ati bori ninu idije naa.

Agbẹnusọ fun ikọ agbabọọlu orilẹ ede yi, ọgbeni Toyin Ibitoye salaye wipe ikọ naa wa ni ipo ti o peye fun idije yi, ti o mu wọn dije daradara pẹlu ikọ Cameroon ninu idije ọlọrẹ-sọrẹ.

Image copyright NFF/TWITTER
Àkọlé àwòrán Ikọ Super Eagles

O wi siwaju pe awọn ọmọ ẹgbẹ agbaọọlu Naijiria CHAN Eagles yi o koju ikọ ọmọ ẹgbẹ agbaọọlu orilẹ ede Rwanda lalẹ ọjọ aje.

Ikọ ẹgbẹ agbaọọlu Naijiria yi o koju ẹgbẹ agbaọọlu Rwanda lọjọ kẹẹdogun osu yi, wọn yi o wọya ija pẹlu ẹgbẹ agbaọọlu Libya ni ọjọ kọkandinlogun osu yi nigbati wọn yi o tako ẹgbẹ agbaọọlu Equitorial Guinea ni ọjọ kẹtadinlogun osu yi.