Walcott: Agbabọọlu Arsenal ti gbaradi lati darapọ mọ Everton

Theo Walcott lori papa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Theo Walcott lori papa

Agbabọọlu lọwọ waju fun ikọ Arsenal, Theo Walcott ti gbaradi lati se ayẹwo eto ilera ni Everton laarin wakati mẹrinlelogun ki o to yọri adehunti o le ni ogun millionu poun.

Ọ ti fara pẹẹ wipe ọmọ ilẹ gẹẹsi ọhun ti o tun jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn ti gba ami ayo ti o gbẹyin fun awọn Gunners ti o darapọ mọ lati inu ikọ Southampton ni bii ọdun mejila sẹyin.

Ireti wa wipe iye ti Everton ko le agbabọọlu naa taayo tawon ẹgbẹ ti o ku tofimọ Southampton.

Lara awọn nkan ti o fa oju Walcott mọnra ni igbiyanju Sam Allardyce lati bomirin ilepa rẹ.

Image copyright Catherine Ivill
Àkọlé àwòrán Theo Walcott lori papa

O ti gba ami ayo ọgọrun kan o le mẹjọ wọle ninu ifarahan bii mẹtadinnirinwo fun ikọ Arsenal, sugbọn ko fi bẹẹ ri oju rere gba lọwọ Arsene Wenger.

Bi adehun naa ba fidi mulẹ, Arsenal yoo lo owo naa lati ra awọn agbabọọọlu tuntun pẹlu ifojusun agbabọọlu Borussia Dortmund Pierre-Emerick Aubameyang ati agabbọọlu Bordeaux, Malcom.

Wọn ni ireti lati ra agbabọọlu Manchester United, Henrikh Mkhitaryan ninu adehun ti yoo kan Alexis Sanchez.