El-Zakzaky: Charlie boy farahan nibi iwọde Shia

Charlie boy farahan nibi iwọde Shia Image copyright CHARLY BOY/TWITTER
Àkọlé àwòrán Charlie boy farahan nibi iwọde Shia

Awọn ọmọlẹyin asaaju ẹsin islam Shia ni, Ibrahim El-zaky zaky tun gunle iwọde loni lati beere fun itusilẹ rẹ.

Amọsa, ohun kan to farahan bi kayefi nibi iwọde wọn oni ni bi gbajugbaja olorin, Charlie boy, se farahan nibi iwọde naa pẹlu awọn ajafẹtọ ọmọniyan kan.

Kayefi ọrọ yii ko sẹyin bi o se jẹ wipe gbogbo ilu lo mọ pe ẹlẹsin Kiristẹni ni Charlie boy, eyi si nmu ki ọpọ maa beere wipe, kilo kan ẹsin pẹlu epo wọn, ki lo kan charlie boy, ẹlẹsin kiristẹni pẹlu itusilẹ El-zakyzaky to jẹ musulumi.

Image copyright CHARLY BOY/TWITTER
Àkọlé àwòrán Charlie boy farahan nibi iwọde Shia

Amọsa, charlie paapaa ti salaye fun awọn eeyan nibi iwọde naa pe, ojoojumọ ni iwọde naa yoo maa waye tit di igba ti ijọba apapọ yoo tu asiwaju ẹsin shia naa silẹ.

Ariwo sọ ni ọsẹ to kọja nigba ti iroyin kan kaakiri pe asiwaju ẹsin shia naa ti ku si atimọle ki o to di wipe o farahan pẹlu iyawo rẹ lopin ọsẹ nibi ti o ti ba awọn oniroyin sọrọ ranpẹ.

Nibayii, awọn agbẹjọro rẹ nke tantan pe, el-zakyzaky ti lugbadi aisan rọparọsẹ; bẹẹni wọnni, ijọba ko tii yọ ọta ibọn to nbẹ lara rẹ latigba ti wọn ti fi si atimọle lọdun 2015.