Niger-Delta: Ẹ maa reti ikọlu

Ẹgbẹ ajijagbara Niger Delta Avengers Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ ajijagbara Niger Delta Avengers

Ẹgbẹ ajijagbara Niger Delta Avengers, ninu atẹjade kan to fi sita lori itakun agbaye ẹgbẹ naa ti sọ wipe, laipẹ jọjọ, awọn yoo se ikọlu si awọn agbegbe to wa ni oriko nibiti awọn ọpa epo robi orilẹede Naijiria wa.

Ẹgbẹ naa lo fi idaniloju han pe, awọn lo se eyi to poju ninu ikolu si awọn eroja ipese epo robi ni orilẹede Naijiria lọdun 2016, eyi to se okunfa adinku to ba ipese epo robi nilẹ Naijiria, pẹlu afikun pe, o le ni milionu kan si meji agba epo rọbi tilẹ wa padanu.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ibudo epo aburo ati betiroolu

Eyi je igba akọkọ larin ọgbọn ọdun, ti iye agba epo rọbi tilẹ wa n pese yoo ja walẹ si milionu kan.

"Awọn ikọlu tọtẹ yi yoo buru jai, yoo si dojukọ awọn ibudo iwapo tawọn ile ise elepo ile okeere to wa lori omi". Eyi je oun ara ohun ti ẹgbẹ ajijagbara Avengers fi ranse lori itakun agbaye wọn.

Ẹgbẹ naa, to n fẹ kijọba apapọ se afikun ipese awọn ohun eelo idagbasoke sagbegbe Niger Delta, tun fikun pe, lara awọn ibudo ti wọn yoo kọlu ni Bonga, Agbami, papa EA, papa Brittania-U ati papa Akpo.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ ajijagbara Niger Delta Avengers

Bẹẹ ba si gbagbe, osu kọkọnla ọdun to kọja, lẹgbẹ ajijagbara naa kede pe awọn ti jebure, bẹẹ si ni lọdun 2016 yi kanaa, ẹgbẹ Niger Delta Avenger kọlu opo eroja ipese epo to wa labẹ omi ni Forcados, eyi ti awọn omuwẹ abẹ omi se.

Lati osu kini ọdun 2017 ni alaafia ti jọba ni agbegbe Niger Delta.