Benue: Saraki pasẹ fun ọga ọlọpa lati wa awọn odaran ri

Abubakar Bukola Saraki Image copyright BUKOLA SARAKI/FACEBOOK
Àkọlé àwòrán Abubakar Bukola Saraki

Wahala awọn darandaran ati agbẹ to ti mu ofo ati adanu ba ọpọlọpọ idile paapa ni ipinle Benue, ti mu ki aarẹ ile asofin agba lorilẹede Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki fun ọga agba ọlọpa, Ibrahim Idris ni gbedeke ọjọ merinla lati fi panpe ọba mu awọn Fulani darandaran to pa aadorin eniyan ni Benue.

Senatọ Bukola Saraki ninu apero naa, sọwipe ijọba apapọ ni lati tun eto aabo se lorilẹede Naijiria, ki ipaniyan to nwaye nipasẹ wahala laarin awọn darandaran ati agbẹ olohun ọsinle le di ohun igbagbe.

Bakannaa lo tun sọpe, bi nkan ti se ri bayii, orilẹede Naijiria nilo apero apapọ lori ọna ati gbe eto abo ka ibi to loorin fun anfani tẹru tọmọ.

Nibi ijoko ileegbimọ asofin agba naa, Ọkọọkan, ejeeji, lawọn asofin agba to wa nibi ijoko ile n mẹnule ẹdun ọkan wọn lori ipaniyan to nwaye nipasẹ wahala laarin awọn darandaran ati agbẹ olohunọsin.

Image copyright BUKOLA SARAKI/FACEBOOK
Àkọlé àwòrán Ile Igbimo Asofin Agba orile ede Naijiria

Bi awọn kan se npe fun atunyẹwo aba lori idasilẹ ọlọpa ẹlẹkunjẹkun, tabi ọlọpa,lawọn miran tun n beere fun idasilẹ ikọ alaabọ alajọse kan laarin ọlọpa atawọn ologun ti yoo fidikalẹ si agbegbe ti wahala naa ti nwaye fun anfani ọjọ iwaju.

Wayi o, Aarẹ ile asofin agba nilẹ Naijiria, Sẹnatọ Bukọla Saraki ko sai tun salaye wipe, ko yẹ ko jẹ awọn ọmọogun ni yoo maa jẹ ibi isadi nigba gbogbo. otun so siwaju wipe "igbesẹ lo kan ni gbigbe lati lee fi awọn ọmọ orilẹede yii lọkan balẹ."

Lẹyin gbogbo atotonu awọn asofin agba naa, wọn wa fi ẹnu ko lori ki ọga agba ileesẹ ọlọpa o fi oju awọn amokunseka to wa nidi ipaniyan ọhun han laarin ọjọ mẹrinla, ki amofin agba ipinlẹ Benue si fi wọn jofin lẹyẹ-o-sọka.

Related Topics