Jose Mourinho fẹ s'adehun ọtun pẹlu ẹgbẹ Man Utd

Adari egbe agbaboolu Manchester United Jose Mourihno Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adari egbe agbaboolu Manchester United Jose Mourihno

Ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti setan lati polongo adehun ọtun ti wọn fẹ se pẹlu adari ẹgbẹ agbaboolu, Jose Mourihno.

Iroyin fi lede wipe ọrọ ti gbera sọ lori adehun tuntun naa, ati wipe o kan ku ki wọn polongo rẹ laipẹ ọjọ ni. Eleyi ti yio mu ki Mourinho duro pẹlu ikọ ẹgbẹ Manchester United ni papa isere Old Trafford.

Ni bi ọjọ diẹ sẹhin, awuyewuye suyọ lori bi ọjọ iwaju Mourihno se sokunkun, ti ohun naa ko jade kuro ni yara ọlọye rẹ fun ọjọ die, lẹyin ti iroyin fi lede wi pe adehun re pelu ẹgbẹ agbaboolu na yoo wa sopin lọdun to n bọ.

Mourinho to je ọmọ ọdunmarundinlogota, nigba ti o fesi si awuyewuye naa, so wi pe iro lasan nipe ọjọ iwaju oun o dan mọ ran pelu egbe agbaboolu naa.

Image copyright OLI SCARFF
Àkọlé àwòrán Adari egbe agbaboolu Manchester United Jose Mourihno

Sugbon ni bayii, iroyin fi lede wi pe, o seese ki adehun tuntun naa o de ọdun 2021.

Monrinho ti o darapo mo ikọ egbe agbabọọlu Manchester United lọdun 2016, ti gba Ife Ẹye (EPL CUP) ati Europa League fun ikọ agbabọọlu Manchester United lọdun ti o darapọ mo wọn.

Ti a o ba gbagbe, yatọ si Sir Alex Ferguson ati Sir Matt Busby to lo ọdun metadinlọgbọn ati Merindinlogun pelu ikọ ẹgbẹ Manchester United, Ron Atkinson lo tun jẹ adari ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United to lo ọdun Marun pẹlu wọn.