Eko: Asọbode ati Onifayawọ wọya ija, ẹmi kan baa rin

Eeyan mẹta lo farapa ninu isẹlẹ yi Image copyright NAN
Àkọlé àwòrán Eeyan mẹta lo farapa ninu isẹlẹ yi

Nse lọrọ di boo lọ, koo ya fun mi laarọ ana nilu Eko, nigbati awọn osisẹ asọbode atawọn afurasi onifayawọ fija pẹẹta ladugbo Abule Ẹgba.

A gbọ pe ọrọ naa di isu ata yan-yan nigba tawọn osisẹ asọbode yin ibọn mọ ọkọ awọn afurasi onifayawọ ọhun, tawọn naa si daa pada, eyi to mu ẹmi eeyan kan, ti wọn orukọ rẹ ni Toyeeb Ọlayiwọla lọ, tawọn eeyan mẹta min si farapa.

Iroyin naa ni awọn osisẹ asọbode ti wọn wa ni Ikẹja nilu Eko ni wọn le ọkọ awọn onifayawọ kan ti wọn furasi pe o ko ọpọ apo irẹsi wọ orilẹede yi wa, ti wọn si gba agbegbe Sango-Ọta wọle, nipinlẹ Ogun wọle.

Bawọn ọkọ naa si se de abẹ afara oloke to wa ni Abule Ẹgba laago marun aarọ, ni wọn ba da ibọn bo ọkan lara awọn ọkọ naa. Ọta ibọn kan la gbọ pe o wọ ọpọlọ Ọlayiwọla, to si gba ibẹ jẹ Ọlọrun nipe loju ẹsẹ.

Image copyright NAN
Àkọlé àwòrán Eeyan mẹta lo farapa ninu isẹlẹ yi

Eeyan mẹta lo farapa ninu isẹlẹ yi

Asiko yi si lawọn osisẹ asọbode yi tun lọ wọ inu ọkọ ẹlẹsẹ mẹta kan to wa nikalẹ, ti wọn si n yin ibọn mọ awọn afurasi onifayawọ naa, ti wọn sọkalẹ lati fi ẹhonu han lori iwa isekupani ọhun, ti wọn si n sọ okuta lu awọn asọbode naa, tawọn onitoun naa ko si dawọ ibọn wọn duro.

Isẹlẹ naa to waye lasiko tawọn eeyan n jade sita lọ sibi isẹ aje wọn, lo mu ki ọrọ naa di koju ma ribi, ẹsẹ loogun rẹ, eyi to tun mu ki eeyan mẹta min farapa. Lẹyin ti ọwọ rogbodiyan naa lọ silẹ, ni awọn eeyan ba faraya, ti wọn si fi ẹhonu han lori isẹlẹ naa.

Image copyright OHI ODIAI
Àkọlé àwòrán Asọbode ati Onifayawọ wọya ija, ẹmi kan baa rin

Awọn Ọlọpa digboluja gan ko gbẹyin nibi isẹlẹ yi

Ọpẹlọpẹ agọ ọlọpa to wa ni adugbo Oke Odo, to tete dasi ọrọ yi, pẹlu iranlọwọ awọn ọlọpa digboluja ati awọn ikọ amusẹya fun ọrọ ayika, bibẹẹkọ, rogbodiyan naa ko ba bọwọ sori.