George Weah se ibura wọlẹ gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Liberia

George Weah ibura gege bi aare orile ede Liberia Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán George Weah ibura gege bi aare ni papa isere niwaju awon eniyan bi egberun marundinlogoji

Wọn ti bura wọle fun George Weah gẹgẹ bi aarẹ tuntun fun orilẹede Liberia. Weah ti figba kan ri jẹ agbabọọlu lagbaye.

Eto pataki ni eyi jẹ fun orilẹede Liberia nitori wipe igba akọkọ niyi latọdun 1944 ti agbara o paarọ ọwọ latọwọ oloselu kan si omiran.

Weah ni aarẹ ikẹẹdọgbọn lorilẹede naa lẹyin to gba ipo lọwọ Ellen Johnson Sirleaf to jẹ aarẹ obinrin akọkọ nilẹ Afirika.

Sirleaf lo ipo naa fun ọdun mejila.

Eto yii waye ni papa isere Samuel Doe to wa nitosi Monrovia tii se olu ilu orilẹede Liberia.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOkodoro ọrọ meje nipa George Weah

Lara awọn eniyan jankan-jankan to peju pesẹ sibi eto ibura wọle ọhun ni aarẹ orilẹede Ghana, Mali, Nigeria ati Togo to fi mọ awọn ọrẹ ati alabasisẹpọ Weah lasiko to fi jẹ agbabọọlu.

Weah sisẹ agbabọọlu nilẹ Yuroopu laarin ọdun 1990 si 2002. Ohun nikan soso ni ọmọ ilẹ adulawọ to ti gba ami ẹyẹ FIFA gẹgẹbi agbabọọlu to pegede julọ lagbaye to fi mọ ami ẹyẹ Ballon d'Or lọdun 1995.

Ireti awọn ọmọ orilẹede Liberia ni wipe Weah yoo mu ileri to se lati pese isẹ ati awọn ileewe to pojuowo sẹ.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Idunu subu layo fun opolopo ni Liberia nibi ayẹyẹ ibura wọle

Ohwefo White ni ti ẹ n "fẹ ki aarẹ wọn tuntun mu idagbasoke ba liigi orilẹede Liberia, ko si tun ran awọn agbabọọlu to jẹ ọmọ Liberia lọwọ lati lọ si ilẹ okeere."

Fatou Sylaani bakanna ni "ki Weah o ni arojinlẹ lori ọrọ awọn ara orilẹede Lebanon ti yoo wa gẹgẹ bi ẹni to fẹ kọ orilẹede Liberia, sugbọn wọn fẹ paarun ni."

Godpower Tamunoala Jumbo ni "ki aarẹ tuntun o gbe orilẹede Liberia lọ si ipele to kan nipa fifi awọn to ni oye nipa imọ ẹrọ ibalode ati idagbasoke yi ara rẹ ka."

Akojọpọ awọn nkan meje to se koko nipa Weah ni yii:

Image copyright Reuters
  • Wọn bii ni ọjọ kinni, osu kẹwa, ọdun 1966
  • O dagba ni agbegbe kan ti awọn ti ko rọwọ họri n gbe ni olu ilu Liberia
  • Okiki rẹ kan lasiko to gba bọọlu fun Monaco fun saa maarun lati ọdun 1987
  • Ohun nikan ni ọmọ Afirika to gba ami ẹyẹ FIFA gẹgẹ bi agbabọọlu to dara julọ lagbaye, to fi mọ Ballon d'Or
  • O fẹyinti gẹgẹbi agbabọọlu lọdun 2002
  • Ọdun 2005 lo kọkọ dije du ipo aarẹ
  • Wọn d'ibo yan an gẹgẹ bi aarẹ ninu osu kejila, ọdun 2017.

Albert Askonnemenjr nfẹ ki "aarẹ Weah ranti wipe irapada lati ọdọ Ọlọrun ni eto isakoso rẹ jẹ fun Liberia."

Awọn ọmọ orileede Liberia ni awọn o maa ranti aarẹ Johnson Sirleaf gẹgẹbi ẹni to mu alafia jọba lorileede naa lẹyin ogun abẹle to waye laarin ọdun 1989 si 2003.

Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán George Weah gba ipo lowo Ellen Johnson Sirleaf gege bi aare orilẹede Liberia

Related Topics