Visionscape: PSP gbàjọ́ba ilẹ̀ kíkó nípìnlẹ̀ Eko

Àkọlé fídíò,

Visionscape ń ṣiṣẹ́ sùgbọ́n...

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko ti paṣẹ̀ pé kí ile iṣẹ́ aládani Private Sector Patnership (PSP) bẹ̀rẹ̀ kíkó ìdọ̀tí padà ní ìpínlẹ̀ Eko.

Adarí ilé aṣòfin náà, Ọ̀gbẹ́ni Mudashiru Obasa to pa àṣẹ yìí lórúkọ̀ àwọn aṣòfin mọ́kàndínlógójì lákòókò ìjókòó ilé sọ pé ilé iṣẹ́ visionscape kò lée tẹ́ ìfẹ́ ìpínlẹ̀ lórí kíkó ìdọ̀tí.

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Awọn òṣìṣẹ́ tí o ń gbá títì olọ́da ní Ékó fẹ̀hónú hán ní ọ́fìsì Visionscape

lórí èyí, wọ́n ti ké sí Kọmísánà fún ọ̀rọ̀ àyíká, Ọ̀gbẹ́ni Babatunde Durosinmi-Etti láti wá fara hàn níwájú ilé lọ́sẹ̀ tó mbọ̀.

Adarí ilé sọ pé ìpínlẹ̀ Eko kò mọ̀ nípa ilé iṣẹ́ Visionscape ó sì tẹnu mọ́ ọ pé ilé ti ta kéte sí ilé iṣẹ́ yìí tipẹ́. Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé ẹ̀ka aláṣẹ ìjọba ò kàn sí àwọ́n kí wọ́n tó gbésẹ́ lé Visionscape lọ́wọ́.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àkọlé fídíò,

'Ìgbésí ayé tí kò pariwo ló dára'

Idọti ipinle Eko: Ile isẹ kolẹkodọti Visionscape bẹrẹ imọtoto ilu

Oríṣun àwòrán, VISIONSCAPE

Àkọlé àwòrán,

Àwọn òṣiṣẹ́ Visionscape kò sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀hónú náà

Awuye wuye ti n lọ fun ọpọlọpọ ọjọ sẹyin, lori bi awọn agbegbe ilu Eko ati awọn ọja rẹ se kun fun idọti, lẹyin ti ijọba ipinlẹ Eko gba isẹ gbigbalumọ lọwọ ajọ LAWMA fun ti wọn gbe fun ile isẹ Visionscape lati maa bojuto imọtoto ayika.

Sugbọn lonii nigba ti ikọ iroyin ile isẹ BBC de ọja Balogun ti awọn idọti pọ si lẹnu bi ọsẹ meji sẹyin, wọn jabọ wipe awọn osisẹ Visionscape ti wọn gba isẹ lẹyin ti ijọba ipinlẹ Eko gbaa lọwọ ajọ LAWMA, ti bẹrẹ si ni ko awọn idọti naa kuro ninu ọja kaakiri.

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ipinlẹ Eko labẹ Gomina Akinwunmi Ambode ti gba awọn osisẹ to le ni ẹgbẹrun mẹjọ abọ si isẹ agbalẹ

Ijọba ipinlẹ Eko ti gba isẹ ikolẹ lọwọ ajọ LAWMA ni ọdun ti o kọja ti wọn si yan wan gẹgẹ bi alamojuto fun ile isẹ kolẹkodọti Visionscape.

Eyi fa idaduro awọn ikọ ile ise akole-kodọti aladani (PSP) ti o se okunfa bi awọn agbegbe ati oju popo nipinlẹ eko se di ibudo ẹgbin fun bi osu mẹfa.

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọkọ akolẹ-kodọti aladani PSP rẹpẹtẹ lo daku soju popo pẹlu idọti ninu wọn

Sugbọn nigbati awọn akọroyin wa bere lọwọ ajọ Visionscape lori imura wọn lati jẹ ki ilu Eko wa ni mimọ, awọn osisẹ wọn kọ lati ba BBC sọrọ, wọn sọ wipe awọn sẹsẹ bẹrẹ isẹ ni.

Ijọba ipinlẹ Eko labẹ isejọba gomina Akinwunmi Ambode sọ lopin ọsẹ wipe awọn ti gba awọn osisẹ to le ni ẹgbẹrun mẹjọ abọ si isẹ agbalẹ. Eleyi, wọn ni yoo pese isẹ fun awọn eniyan ati wipe awọn agbalẹ naa yoo fopin si dida ilẹ soju opopona marosẹ to wa ni awọn agbegbe ipinlẹ Eko.

Àkọlé àwòrán,

Ile isẹ to n ja fun ọrọ imọtoto agbegbe tako ile ise Visionscape

Ẹwẹ, ile isẹ to nja fun ọrọ imọtoto agbegbe, (The Environmental Rights Action/Friends of the Earth Nigeria -ERA/FoEN) ninu atẹjade ti wọn fi sọwọ si ile isẹ iroyin BBC Yoruba tako bi ijọba ipinlẹ Eko se gba ile isẹ Visionscape lati maa se imọtoto ni ipinlẹ Eko.

Ile isẹ naa wipe Visionscape ko kun oju osuwọn lati dẹkun ọrọ idọti to wa loju popo, nitori wipe wọn ko se imọtoto ipinle Eko lati igba ti wọn ti gbe isẹ ohun le wọn lọwọ ni ọdun to kọja.