Aso Rock: Idi ti eku fi wa ni ile ijọba apapọ

Jalal Arabi,akọwe agba ni Aso Rock Image copyright Jalal Arabi/Twitter
Àkọlé àwòrán Ounje to wa ni aso Rock ti pọju

Akọwe agba nile ijọba apapọ (Aso Rock), Jalal Arabi ti sọrọ lori idi ti eku fi wa nile Ijọba nilu Abuja.

Arabi ni idi abajọ ni pe, Abuja funrarẹ jẹ ilu to sọlẹ sori oke, ti ọpọlọpọ apata si yii ka, ati pe, orisirisi awọn nnkan jijẹ lo kun fọfọ sile ijoọba eleyii to le sokunfa awọn eku.

Ti a ko ba gbagbe, nigba kan sẹyin, lẹyin ti aarẹ de lati ilu London nibi ti o ti lọ gba itọju, a gbọ pe awọn eku ko jẹ ki aarẹ wọ ọfiisi rẹ to wa ni'le ijọba.

Eyi lo mu ki sẹnatọ kan, Joshua Lidani beere lọwọ akọwe ile ijọba apapọ bi wọn ba ti pese eroja ifinle sile ijọba ti yoo le awọn eku.

Àkọlé àwòrán Ounje wa ni yanturu nile ijọba apapọ

Arabi dahun, o sọ pe ofin to de pipa awọn ẹranko lagbaye ko faaye gbawọn lati dẹkun bi awọn eku naa se n rin ka nile ijọba.

Awọn aramanda eku yii ni agbẹnusọ fun ijọba apapọ, ogbẹni Femi Adesina sọ pe wọn jẹ awọn aga ati tabili ti aarẹ fi n joko l'ọdun to kọja.