Awọn Ibẹẹta pẹlu ọmọ iya wọn jona mọle ni jigawa

Irin igbomikana Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Irin igbomikana lewu lasiko ọyẹ

Awọn ibẹta kan ati ọmọ iya wọn lọkunrin ti jona mọle nilu Hadejia nipinlẹ Jigawa.

Adamu Shehu to je alukoro fun ajọ ẹlẹto abo ara ẹni labọọlu (Nigeria Security and Civil Defence Corps) lo kẹdẹ ọrọ naa.

Shehu sọ fun ile isẹ iroyin News Agency of Nigeria pẹ ina naa sẹyọ latara irin igbomikana (boiling ring) ni nkan bi agogo mọkanla alẹ lọjọ abamẹta ọgunjọ osu yi.

Hassan Sale, Hussaina Sale ati Muhusin Sale lorukọ awọn ibẹta ti o padanu ẹmi wọn ninu isẹlẹ naa ti orukọ ọmọ iya wọn ọkunrin naa njẹ Aliyu Sale.

Shehu s'alaye pẹ ni ile awọn ibẹta ni ina ti sẹyo. Ọpo dukia lo si baa lọ.

O rọ awọn ara'lu pe ki wọn ma a sọra pẹlu awọn ẹrọ to'n ba ina sisẹ paapa julọ lasiko ọyẹ.