EPL: Òmì 2-2 ni Chelsea àti Manchester United gbá

Ross Barkley

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Òmì ni Chelsea ta pẹ̀lú Man U

Ẹni to ba foju ana wo oku, ẹbọra ni yoo bọ onitọun lasọ. Bẹẹ gẹgẹ ni ọrọ ikọ Manchester United jẹ lẹyin ti wọn na Chelsea mọle.

Ọpọ lo ro pe alubami ni Chelsea yoo lu Man U saaju ifẹsẹwọnsẹ ọhun, ṣugbọn awọn agbabọọlu ikọ Man U ya ọgọrọ ololufẹ ere bọọlu lẹnu lẹyin ti wọn ta omi alayo mejimeji pẹlu Chelsea

Koda diẹ bayii lo ku, wọn o ba na Chelsea mọle ni papa isere Stamford Bridge.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn Ross Barkley ti wọn gbe wọle fun Mateo Kovacic lo gbayo keji wọle fun Chelsea nigbati ifẹsẹwọnsẹ naa.

Antonio Rudiger lo kọkọ gbayo sawọn fun Chelsea, sugbọn Anthony Martial sọ ere bọọlu naa di omi alayo kọọkan nigba to dayo naa pada.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Anthony Martial gbáyò sáwọ̀n fún Man Uinted

Lai besu bẹgba, Martial tun ṣe bẹẹ o tun gbayo ẹlẹẹkeji wọle ṣugbọn omi ni ere bọọlu naa pari si.

Jose Mourinho ni wọn n ditẹ mọ oun

Nnkan ko fara rọ pẹlu akọnimọọgba ikọ Manchester United Jose Mourinho lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu naa kuna lati fakọyọ ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ kan ti wọn gba laipẹ yii.

Koda, Mourinho ni bi awọn oniroyin ere idaraya ti n tako ikọ Man U n sakoba fun awọn agbabọọlu ikọ naa.

Ọpọ oniroyin ati awọn agbabọọlu to ti fẹyinti tilẹ sọ pe Mourinho le padanu iṣẹ rẹ ti Manchester United ba fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ ọjọ Abamẹta.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Chelsea àti Manchester United wàákò ní pápá ìṣeré Stamford bridge

Ṣugbọn akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea Maurizio Sarri sọ pe ikọ Manchester United lo ni awọn agbabọọlu to pegede julọ saaju ifẹsẹwọnsẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Gbẹgẹdẹ yóò gbiná nígbà tí Eden Hazard àti Paul Pogba bá kojú ara wọn

Mourinho ti figba kan ri jẹ akọnimọọgba ikọ Chelsea nibi ti o ti gba ife ẹyẹ Premier League lẹẹmẹta pẹlu ikọ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Chelsea ló kọ́kọ́ gbáyò wọlé

Sugbọn ta ni yoo jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ t'ọjọ Abamẹta? Ipade dori papa ni Stamford Bridge nilu London.