Manchester Utd lo n pawo wọle julọ lẹka ere bọọlu

Paul Pogba Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aseyọri Man Utd lẹnu lọọlọ yi ko sẹyin Paul Pogba

Ẹgbẹ agbabọọli Manchester United lo n lewaju lọwọ-lọwọ lori tabili awọn ẹgbẹ agbabọọli ogun lagbaye lati ọdun meji sẹyin, to si ti wa nipo naa fun igba mewa gbako.

Akọsilẹ tuntun ti fi han pe, taa ba wo awọn owo ti wọn na, ninu idije liigi fun saa ere bọọlu lọdun 2016 si 2017, aridaju wa pe owo to n wọle fawọn ẹgbẹ agbabọọlu bii ogun ti fo lọ soke pẹlu ida mẹfa ninu ọgọrun, to si ti di biliọnu lọna mẹjọ o din diẹ owo Ero (€7.9bn, $9.7bn).

Ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid lo wa nipo iwaju fun ọdun mọkanla, lo se ipo keji, ti ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona si se ipo kẹta.

Akọsilẹ fi han pe ẹgbẹ agbabọọlu mẹwa to n kopa ninu idije liigi ilẹ gẹẹsi lo wa ninu awọn ogun agbabọọlu to lowo julọ naa.

Kikida awọn owo to n wọle fawọn agbabọọlu naa nikan ni akọsilẹ naa se, ti ko si se iwadi nipa awọn gbese ti wọn jẹ. Bẹẹ si ni ifigagbaga fun ipo kinni lọdun yi laarin awọn ẹgbẹ agbabọọlu to lowo julọ naa, lo tii sunmọra julọ, nitori owo Ero bii miliọnu meji o din diẹ lo jẹ iyatọ laarin ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ati Real Madrid.

Awọn ẹgbẹ agbabọọlu to lowo julọ ti Deloitte se:

Image copyright AFP
  1. Manchester United: €676.3m
  2. Real Madrid: €674.6m
  3. Barcelona: €648.3m
  4. Bayern Munich; €587.8m
  5. Manchester City: €527.7m
  6. Arsenal: €487.6m
  7. Paris Saint Germain: €486.2m
  8. Chelsea: €428m
  9. Liverpool: €424.2m
  10. Juventus: €405.7m

Orisun Iroyin: Deloitte.