Ọlọpaa ti fi Oby Ezekwesili sile wọn si ti ni ko maa lọ sile

Oby Ezekwesili, oludari ẹgbẹ 'Bring Back Our Girls' Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Oby Ezekwesili ti n fi ehonu han loojumọ nilu Abuja fun awọn ọmọbinrin Chibok

Awọn olopaa ti fi Oby Ezekwesili sile, o si ti kuro ni ahamọ wọn. Loni ni wakati diẹ seyin, ni awọn ọlọpaa mu arabinrin to jẹ oguna gbongbo lara awọn oludasile ẹgbẹ Bring Back Our Girls (BBOG) ati awon ọmọ ẹgbẹ ọun kan si ahamọ nilu Abuja.

Awọn eniyan ti bu ẹnu atẹ lu awọn ọlọpaa lori ọrọ yi, ti wọn si ni ki wọn fi Ezekwesili silẹ.

Ezekwesili lo fi ọrọ naa sọwọ lori oju opo Twita rẹ.

O se alaye pe isẹlẹ ọun ni se pẹlu bi awọn ti se'n beere fun itusilẹ awọn ọmọ ile ẹkọ Chibọk ti awọn Boko Haram jigbe.

Igbiyanju wa lati ba alukoro ọlọpa Abuja Jesse Manzah sọrọ jasi pabo. Ko da ipe wa pada, sugbọn ninu oun ti Ezekwesili fi sọwọ ninu ọrọ lori Twita, o fi han wipe ni ile isẹ ọlọpa ilu Abuja ni wọn ko wọn lọ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ BBOG miran ti gba ori ẹrọ ayelujara Twita lati kede mimu ti ọlọpa mu wọn.

Eyi kii se igba akọkọ ti awọn ọmọ ẹgbẹ Bring Back Our Girls yoo ma ni ikọlu pẹlu ọlọpa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ezekwesili ti bu ẹnu ẹtẹ lu awọn ẹgbẹ oselu APC, PDP

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa bi o ba se tẹwa lọwọ.