Ọwọn Epo: Awọn eniyan n ke gbajare ailọdeede ọrọ aje

Ijọba wipe awọn ko ni ipinu lati fi kun owo epo, sugbọn ọpọlọpọ ko ri epo ra Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ijọba wipe awọn ko ni ipinu lati fi kun owo epo, sugbọn ọpọlọpọ ko ri epo ra

Awọn agbegbe kan ni ipinlẹ Eko ni iroyin ti sọ pe wọn si n la ọwọn gogo epo petiroo kọja.

Ti a ko ba gbagbe, laipẹ yii ni ọwọn epo petiroo se n kase nlẹ lorilẹ-ede Naijiria lẹyin ti ijọba kede pe awọn ko nii lọkan lati fi owo kun owo epo ọhun.

Lẹyin eyi ni awọn olugbe awọn agbegbe ipinlẹ Eko bii Agege, Ketu-Ojota, Mushin ati bẹẹbẹẹlọ ti ke gbajare pe laarin otalelọọdunrun o din mẹwaa ati irinwo naira ni awọn n ra jala epo petiroo kan.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ogunlọgọ awọn eniyan ke gbajare ailọdeede ọrọ aje fun asiko ti wọn nlo nile epo

Awọn olugbe agbegbe ọhun sọ pe o seni laanu pe ninu ohun ti o to ogun ile-epo, meji pere lo n ta epo ni ọgọrun meji naira ni agbegbe Ketu ati ni agbegbe Obalende.

Ọwọn epo to waye lawọn agbegbe yii ni iroyin ti sọ pe o ti sokunfa ailọdeede ọrọ aje fun awọn eniyan wonyii.

Awọn eniyan yii ni wọn ti ke gbajare si ijọba lati ba wọn wa ojutu si ọrọ naa.

Ile epo petiroo ji ko ba taja yoo di titi pa

Ajọ DPR ti awọn ile epo kan to n ko epo pamọ ati awọn ti wọn nfikun owo epo.

Ajọ to n risi idiyele owo epo betiro DPR so wipe won ti ti awọn ile epo kan to n ko epo pamo ati awọn ti wọn nfikun owo epo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKi ni o mọ to n jẹ owo iranwọ epo?

Ilẹ isẹ epo rọbi orilẹede Naijiria ti kesi gbogbo araalu lati kọ ipakọ si iroyin ti o niise pẹlu alekun owo epo bẹtiro.

Ninu ọrọ rẹ, minista abẹle fun ọrọ epo rọbi, Ibe Kachikwu tẹpẹlẹ mọọ wipe ile isẹ oun ti se agbende igbimọ kan lati jiroro lori idiyele ori epo bẹtiro, pẹlu alaye wipe igbimọ naa yio jabọ fun aarẹ orilẹedẹ yii leyin isẹ iwadi wọn.

Image copyright DPR/TWITTER
Àkọlé àwòrán Awọn ile epo kan ti n sofo owo epo lẹhin ti ajọ DPR ti n fun awọn ara ilu lepo ọfẹ

Iroyin ọhun tẹsiwaju wipe alakoso ikeji fun epo rọbi ko sọ ohunkohun ti o jọ mọ alekun owo epo ninu ọrọ rẹ nibi apero kan ti o da lori alumọni epo rọbi.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Owon gogo epo kan gbogbo eniyan nilu