Arun iba ọrẹrẹ Lassa: dokita kan jalaisi nipinlẹ Kogi

Eku ile
Àkọlé àwòrán ogunlọgọ awọn eniyan lo ti doloogbe nipasẹ arun iba ọrẹrẹ

Ijọba ipinlẹ Ondo ti n lọgun bayi pe eniyan marun ti jalaisi lati ipasẹ arun iba ọrẹrẹ ati wipe eniyan mejilelogun miran ti wa labẹ itọju ni ipinlẹ naa.

Kọmisọnna feto iroyin nipinlẹ Ondo, Yẹmi Owolabi sọ pe eniyan mejidinlogun lo wa labẹ itọju iba ọrẹẹrẹ lati agbegbe ijọba ibile Ọwọ, ti meji miran si tun wa lati ijọba ibilẹ Guusu-Akure, ti ọkan tun wa lati Ariwa-Akurẹ ati mẹji miran lati Iwọ-Oorun ijọba ibilẹ Akoko.

Owolabi fikun pe, awọn eniyan to ku naa wa lati ijọba ibilẹ Ọse, ati wipe aisan iba ọrẹẹrẹ naa ti tan yika awọn ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Ondo.

Tẹẹ ba gbagbe, Osu Kefa ọdun to kọja ni eniyan marun fara gba arun iba ọrẹrẹ, sugbọn ti awọn onimọ ijinlẹ tete ka ọwọja arun naa ko lẹkunrẹrẹ.

Eniyan Mẹrinlelogoji n gba itọju ni ijọba ibilẹ AriwaKogi

Àkọlé àwòrán Iba ọrẹrẹ pa alaisan, o tun pa dokita to n tọju wọn

Bakanna nipinlẹ Kogi, Dokita kan to n sisẹ nile-iwosan ijọba apapọ to wa ni Lọkọja, Idowu Ahmed ti dologbe nipasẹ aisan iba ọrẹrẹ, ti eniyan mẹrinlelogoji si wa ni ile iwosan, ti wọn n gba itọju ni ijọba ibilẹ Ariwa-Kogi.

Oludari agba nile-iwosan ijọba apapọ to wa nipinlẹ Kogi, Dokita Olatunde Alabi sọ pe gbogbo awọn to wa labe itọju ni wọn ti ya sọtọ fun itọju, nitori wọn ni ifarakanra pẹlu Dokita to dologbe naa.

Ijoba ipinlẹ Koji so siwaju wipe, awọn yoo koju aisan naa nipa siseto ilanilọye fun awọn araailu, lati ri wipe aisan naa ko tan ka ibugbe kankan.

Aisan iba ọrẹrẹ jẹ aisan to wa lara awọn eku ile, to si le tan ka ara eniyan, nipa ounje tabi ohun elo ile, ti eku naa ba ni ifarakanra pelu.