CHAN 2018: Super Eagles sunmọ asekagba CHAN nigbati wọn fagba han Equitorial Guinea

Anthony Okpotu leyin to gba ayo wọ inu awọn Image copyright Complete sports
Àkọlé àwòrán Naijiria fagba han Equitorial Guinea

Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti fakọyọ, to si ti yege lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ to sikeji si asekagba ninu idije fun ife ẹyẹ larin awọn agbabọọlu Ilẹ Africa taa mọ si CHAN.

Ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria, to koju iko Equatoria Guinea ni ko kọkọ gba ami ayo kankan wọle ni abala kinni idije naa, to di pe igba yipada fun wọn ni saa keji, ti wọn si na ikọ Equitorial Guinea pẹlu amin ayo mẹta si ọkan.

Equitorial Guinea to saaju ni ibẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu amin ayo kan ti Nsi Eyama gba wọle, lo fidi rẹmi nigba ti awọn atamatase Super Eagles, Anthony Okpotu, Dayo Ojo ati Rabiu Ali gba ayo sinu awọn ni saa kẹji ifẹsẹwọnsẹ naa.

Pelu aseyọri yi, Super Eagles ti leke tente sipo kinni ni isọri kẹta, pẹlu amin meje ninu ifẹsẹwonsẹ mẹta. Ẹgbẹ agbabọọlu Libya, ti wọn na ẹgbẹ agbabọọlu Rwanda pẹlu amin ayo kan sodo, naa yege sipo kẹji ni isọri kẹta idije CHAN to n lọ lọwọ.