Awọn ọmọ ile-iwe joko sile nitori iyansẹ̀lodi ọlọ̀jọ̀ mẹ̀ta ni ipinlẹ

Image copyright NLC WEBSITE
Àkọlé àwòrán Ijọba le awọn osisẹ̀ LAUTECH ti iye wọ̀n jẹ̀ Igba o lẹ̀ Mẹ̀rindinlọ̀gọ̀ta kuro lenu isẹ

Gbogbo awọn Ile-iwe ti ijọba ipinlẹ̀ Ọ́yọ̀ wa ni titi pa loni, nitori iyansẹ̀lodi ọlọ̀jọ̀ mẹ̀ta, lati kilọ́ fun ijọba ipinlẹ̀ Ọ́yọ̀, lati da awọn osisẹ̀ LAUTECH to je Igba o lẹ̀ Mẹ̀rindinlọ̀gọ̀ta ti wọ́n da duro, pada sẹ́nu ise.

Iwadi ti BBC News,Yoruba se loni, tifi idi re mulẹ wipe, ni ijọba ibilẹ̀ Lagelu ati ijọba ibilẹ̀ Ariwa-Ibadan, awọn akẹ́ẹ̀kọ́ ko lọ sile iwe, bẹ́ẹ̀ si ni awọn olukọ́ ko kuro nile wọn. Sugbon, diẹ́ lara awon osisẹ̀ ijọba lọ si ibi isẹ́ won, ti ọ́pọ́ si joko sile.

Iroyin fi lede wipe ẹgbẹ awọn osisẹ̀ labẹ̀ NLC, TUC ati JNC to pe fun iyansẹ̀lodi ọlọ̀jọ̀ mẹ̀ta onikilọ̀ naa, so fun awọn osisẹ̀ ni ipinlẹ̀ Ọ́yọ̀ lati fi kọ́kọ́rọ́ ti ile-isẹ́ wọn fun ọjọ mẹ́ta, eleyi ti o bẹ́rẹ́ loni.

Image copyright NLC WEBSITE
Àkọlé àwòrán Iyansẹ̀lodi wọ̀pọ́ lorilẹ́ede Naijiria

Adari egbe osisẹ̀ NUT nipinlẹ̀ naa, Comrade Niyi Akano, nigba ti o ba BBC sọ́rọ́, wipe ki ijọba ipinlẹ̀ Ọ́yọ̀ wa ọ́na abayọ si iyansẹ̀lodi ọlọ̀sẹ́ mẹ̀tala ti awọn osisẹ̀ ile-isẹ́ giga ti ijọba ipinlẹ̀ Ọ́yọ̀ gun le. O tun wipe, ki ijọba ipinlẹ̀ naa da awọn osise ti wọn da duro lẹ́nu isẹ́ ni Ile-Iwosan Ikẹ́ẹ̀kọ́ Isegun ti ijọba ipinlẹ̀ Ọ́yọ̀ LAUTECH, pada sẹnu ise.

Akano tẹ́ siwaju wipe, lara ohun ti o tun sokunfa iyansẹ̀lodi naa ni bi ijọba ipinlẹ̀ Ọ́yọ̀ se kọ́ lati sanwo ifeyinti ati owo ajemọ́nu awọn osisẹ̀feyinti ni Ile-Ekọ̀ Alakọ́bẹ́rẹ́, eleyi ti o n lọ si bi osu mẹ̀rindinlaadọ̀ta.

O tun fi kun wipe, awọn gun le iyanselodi naa lati fi ehọ́nu wọn han, ati lati duro sinsin pẹ́lu awọn Igba o lẹ̀ mẹ̀rindinlọ̀gọ̀ta osise, ti wọn le kuro lẹ̀nu isẹ́ ijọba ni ipinlẹ́ naa.

Amo, igbiyanju wa lati beere iha ti ijọba ipinlẹ̀ Ọ́yọ̀ ko si iyansẹ̀lodi ọlọ̀jọ̀ mẹ̀ta naa jasi paabo, nigba ti oludamoran fun Gomina ipinlẹ̀ Ọ́yọ̀ lori eto iroyin, Ogbeni Yemi Olayinka ko gbe ipe erọ ibanisọ́rọ́ wọn.