Thierry Henry so wipe oun ko sọ fun Sanchez ki o lo si Man U

Thierry Henry ti ni ohun kọ́ lohun sọ fun Sanchez lati kuro ni Arsenal Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Okoolerugba le mẹ́jọ igba ni Henry gba bọ̀ọ́lu sinu awọ̀n fun Arsenal

Ogunna gbongbo ninu ẹgbẹ agbabọ́ọ̀lu Arsenal,Thierry Henry ti sọ̀ pe ohun o sọ fun Alexis Sanchez lati kuro ni Arsenal .

Sanchez to darapọ mọ Manchester United lọ́jọ́ aje ninu eto pasi- paarọ̀ to waye laarin ohun ati Henrihk Mkhitaryan ni ohun ba Henry sọ̀rọ̀ lori igbesẹ̀ oun.

Ninu akọsilẹ̀ kan to fi si oju opo Instagram, o ni ''loni, mo ranti itakurọ̀sọ ti mo ni pẹ̀lu Henry ti ohun naa paarọ̀ ẹgbẹ́ agbabọ̀ọ́lu to n ba sisẹ nitori eredi kan naa ti ọpọn rẹ̀ sun kan emi naa loni.''

Henry to fi Barcelona silẹ̀ ni 2007 fesi lọ́jọ́ isẹ́gun pe "Kosi igba kan kan ti mo sọ fun Alexis Sanchez lati kuro ni Arsenal."

Nigba tohun fesi lori ẹ̀sun ọ̀un lori Twitter, o ni "mi o ni oye pe Sanchez yoo ti ọwọ́ bọ iwe adehun pẹ̀lu Man Utd, afi igba ti mo ri ninu iroyin bi ẹ̀yin iyooku naa se ri."

Henry, ẹni ogoji ọdun darapọ̀ mọ́ wọn ni Nou Camp lẹ́yin to lo saá mẹ́jọ pẹ̀lu Arsenal gba ife ẹ̀yẹ La Liga lẹ̀ẹ́meji, to fi mọ́ Champions League ninu ikọ̀ agbabọ́ọ̀lu naa.

Sanchez, ẹni ọdun mọ́kandinlọ́gbọ̀n, to tun jẹ́ agbabọ̀ọ́lu iwaju fun orileede Chile tọwọ́ bọ iwe adehun ti owo rẹ le ni miliọ́nu mọ́kandinlogun lọ́dọọdun fun ọdun mẹ́ẹ̀rin ataábọ̀ pẹ̀lu Man Utd.

Related Topics

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí