Fayose sọrọ lori lẹta Ọbasanjọ si aarẹ Buhari

Fayose sọrọ lori lẹta Ọbasanjọ si aarẹ Buhari

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose ti se apejuwe awọn koko inu lẹta ti oloye Ọbasanjọ kọ ransẹ si aarẹ Buhari gẹgẹbi eyi to se rẹgi ero ọkan araalu.

Sugbọn Fayose ni bi oju akata ba le owo, kii se ẹnu adiyẹ lo ti yẹ ki o ti jade atipe kii se Oloye Ọbasanjọ lo yẹ ko ti ẹnu rẹ jade nitori, gẹgẹbi o se sọ, oloyẹ Ọbasanjọ kun ara awọn to sun orilẹede Naijiria de ibi to wa loni.

Bakanna lo ke si oloye Ọbasanjọ wi pe asiko to fun oun naa lati fi agbo oselu silẹ patapata.