EFCC ju akọwe ijọba Babachir silẹ

Akọwe ijọba ilẹ Naijiria nigbakanri, ọgbẹni Babachir Lawal Image copyright @GarShehu
Àkọlé àwòrán Akọwe ijọba ilẹ Naijiria nigbakanri, ọgbẹni Babachir Lawal n dahun ibeere lori ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan-an.

Akọwe ijọba ilẹ Naijiria nigbakanri, ọgbẹni Babachir Lawal ti gba ominira lati lọ sile lọwọ ajọ EFCC.

ọgbẹni Babachir Lawal ti wa ni ahamọ fun ifọrọwanilẹnuwo lati ọjọru.

Alukoro ajọ EFCC, ọgbẹni Samin Amadin sọ fun BBC Yoruba pe Babachir Lawal ti dahun awọn ibeere ti o jọ mọ iwa ibajẹ nigbati o wa nipo ijọba.

O ni iwadi si nlọ lọwọ lori ẹsun ti wọn fi kan an ati wipe awọn idahun ti o fesi lori ibeere yoo se iranlọwọ fun ajọ naa lati ni aridaju ẹsun.

Babachir salaye ara rẹ lori ẹsun pe o se owo ti o to igba miliọnu naira to yẹ fun nina fun gige koriko lọgba awọn ti wahala le kuro nile lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria, basubasu.

Aarẹ Buhari yọ Babachir Lawal nipo losu kẹwa ọdun 2017 lẹyin ti igbimọ ti wọn gbe kalẹ lati tan ina wadi ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan-an gbe aba tọ aarẹ lọ wi pe ko yọ ọ ni ipo.