Shehu Abdullahi darapọ mọ Bursaspor ni Turkey

Shehu Abdullahi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Shehu Abdullahi je ami ayo meta ninu iwọnse mejidinlaadọta fun ẹgbẹ agbabọọlu Anorthosis Famagusta nigba to' ngba fun wọn

Agbabọọlu ẹyin fun orilẹede Naijiria, Shehu Abdullahi ti fi ẹgbẹ agbabọọlu Anorthosis Famagusta ilẹ Cyprus silẹ lati darapọ mọ Bursaspor ilẹ Turkey fun ọdun meji ati abo.

Ọmọ ọdun mẹrinlelogun naa darapọ mọ Anorthosis Famagusta lati ẹgbẹ Uniao da Madeira ilu Portugal losu kẹsan ọdun 2016.

Abdullahi, to ti gba bọọlu ri ni ilẹ Kuwait ati Portugal, yoo darapọ mọ awọn akẹgbe rẹ William Troost-Ekong, Mikel Agu ati Paschal Okoli ni Bursaspor labẹ akọni Paul Le Guen to ti dari ikọ agbabọọlu ilẹ Cameroon ni igba kan ri.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Abdullahi gba fun Naijiria ninu idije awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn ko kọja ogun ọdun nilẹ Turkey lọdun 2013

Abdullahi sọ fun BBC Sport pe "Mo dupẹ lọwọ Anorthosis Famagusta fun irinajo mi pelu wọn, inu mi si dun lati je ọmọ ẹgbe agbabọọlu Bursaspor "

Ni ọdun to pari adehun rẹ pẹlu ẹgbe naa ni ilu Cyprus, iroyin gba'le kan pẹ o se e se ki o darapọ mọ Birmingham City sugbọn o yi ọkan pada lati gba fun ẹgbe to lorukọ ki o baa lee ribi wa lara awọn ti yoo kopa ninu idije bọọlu agbaye.

Abdullahi gba fun Naijiria ninu idije awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn ko kọja ogun ọdun nilẹ Turkey lọdun 2013.

Bakanna lo kopa nigbati Naijiria se ipo kẹta nibi idije African Nations Championship (CHAN) ni ọdun 2014 ni South Africa.