Ibudo ikepo si bu gbamu nipinlẹ eko

Ibudo ipamọ epo betiroo nilu eko Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán Ko si ẹmi ti o padanu ninu iṣẹlẹ naa

Ibudo ipamọ epo bẹtiroo kan ti o ni awọn agba ikepopamọsi nlanla marun (PMS) ti gba ina jẹ ni agbegbe Ijegun nilu Eko lọjọọru.

Ile-iṣẹ Isakoso ipe pajawiri ni ipinlẹ Eko (LASEMA) sọ fun BBC pe ijamba ibugbamu ina yii sẹlẹ ni ileesẹ epo Stallionaire Oil ni nkan bii agogo mẹta ọsan.

Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán LASEMA npe fun ohun elo fun isẹlẹ pajawiri lẹnu isẹ ati ni ibudo ipam epo gbogbo

Oludari ile isẹ LASEMA, Ọgbẹni Adesina Tiamiyu sọ pe awọn osisẹ rẹ gbiyanju lati pa ina naa ni kiakia ti wọn ti fi to wọn leti, ti wọn si dẹkun ibugbamu ina yi fun awọn agba ikepopamọsi yooku ni ile isẹ naa.

O wi pe iwadi ti o peye yoo waye lori isẹlẹ naa, nigbati o tẹnumọ iwulo fun awọn onile-epo ati afẹfẹ gaasi lati rii daju wipe eto wa fun awọn ohun eelo idojukọ isẹlẹ pajawiri lẹnu isẹ ati ni ibudo ikepopamọsi gbogbo.

Ko si ẹmi to ba iṣẹlẹ naa lọ.

Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán Eyi jẹ ijamba ibugbamu inọ epo ati gaasi ti yoo sẹlẹ nipinlẹ eko ninu osu yi