Arun Iba: Naijiria gbaradi fun eto ajẹsara to pọ julọ

Abẹrẹ ati oogun oyinbo fun arun iba Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Orilẹ ede Naijiria ti setan la bẹrẹ eto ajesara to pọ julọ

Ni ọjọru, orilẹ ede Naijiria yoo bẹrẹ ipolongo ati isẹ ajesara lati daabo bo awọn eniyan ti o to bii miliọnu mẹẹdọgbọn.

Ijọba Naijiria, pẹlu ajọ alamojuto fun eto ilera agbaye (WHO) pẹlu ajọ UNICEF, ti ṣe ipinnu lati gbe ipolongo naa ni ọdun yi, eyi ti yoo idẹda ajesara ti o tobi julọ ti orilẹ-ede yi ti se.

O jẹ ipele kan ninu igbiyanju agbaye gbogbo lati dẹkun arun iba apọnju ni ọdun 2026; eyi yoo bẹrẹ ni orilẹ ede Naijiria ni ipinle Kogi, Kwara ati Zamfara.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn eniyan marundinlaadọta ti salaisi latari arun iba-pọnju, pọntọ.

Nibayi, Naijiria n dojuko ibẹsilẹ arun iba-pọnju eyiti o bẹrẹ ni iwọ-oorun orilẹ ede ni oṣu kẹsan ọdun to kọja.

Ni opin ọdun 2017, o ti ṣe eto ajẹsara fun awọn eniyan ti o le ni miliọnu mẹta, ṣugbọn eyi ko da itankalẹ arun naa duro.

Ni ibẹrẹ ọdun yii, awọn eniyan marundinlaadọta ti salaisi latari arun iba-pọnju, pọntọ.