Ayẹyẹ ètò ìsìnkú Alex Ekwueme wá s'ópin lònìí

Oloogbe Alex Ekwueme
Àkọlé àwòrán Bi onirese Alex Ekwueme ko ba fin igba mọ, eyi to ti fin silẹ ko lee parun.

Gẹ́gẹ́ bí ètò ayẹyẹ ìsìnkú Alex Ekwueme tó jẹ́ igbákejì àárẹ àkọ́kọ́ fún orílẹ̀èdè Nàìjíríà ṣe ń wáyé lónìí ní ìpínlẹ̀ Anambra, dìẹ̀ lára ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ nìyíì:

 • Ó jẹ́ igbákejì àárẹ àkọ́kọ́ fún Nàìjíríà láàrin ọdún 1979 sí 1983
 • Ó díje lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òsèlú National Party of Nigeria
 • Wọ́n bí i ní ọjọ́ kọkànlélógún,oṣù kẹwàà, ọ́dún 1932
 • Ó jẹ́ ọmọ ìlú Oko nijọba ìbílẹ̀ Àríwá Orumba ní ìpínlẹ̀ Anambra
 • Ó dágbére fáyé lọ́jọ́ ìkọkàndìnlógún, oṣù kọkànlá, ọdún 2017 lẹ́ni ọdún máàrúnlélọ́gọ́rin
 • Ekwueme jẹ oyè Ide ni ìlú Oko kingdom ní ìpínlẹ̀ Anambra, níbití, àbúrò rẹ̀, Lazarus, ti jẹ́ oríadé.
 • Ó ṣiṣẹ́ ní ESSO West Africa, tó wà ní ìlú Èkó, gẹ́gẹ́ bí olùdarí ẹ̀ka ilé kíkọ́
 • Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ St John's Anglican Central School ni Ekwulobia, kó tó lọ sí King's College, ní ìpínlẹ̀ Èkó.
 • Ekwueme lọ sí Fásitì ìlú London; ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin Nàìjíríà; Fásitì ìlú Strathclyde àti Fásitì ìlú Washington.
 • Ó se ìdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Ekwueme Associates, Architects and Town Planners, to jẹ́ iléeṣẹ́ ayàwòrán ilé akọ́kọ́ látọwọ́ ọmọ Nàìjíríà
 • Òun ni olórí ikọ̀ ònòwòye níbi ètò ìdìbò àárẹ àti iléègbìmọ̀ aṣòfin Tanzania lọ́dún 2000.
 • Ekwueme tún jẹ́ ọmọ ìgbìmọ̀ àwọn àgbàgbà nínú àjọ ECOWAS

A ó máa fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí ètò nàá ṣe ń lọ tó yín létí.