Trump::Lakọ ni wo wa lati koju iwadi lori ibo aare 2016

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Isejọba aarẹ Donald Trump ti pe ọdun kan

Aare Donald Trump ti sọ wipe ohun foju sọna fun ifọrọwanilẹnuwo ninu iwadi to n lo lọwọ, lori ẹsun wipe orilẹede Russia dabaru idibo sipo Aare ilẹ Amẹrika lọdun 2016.

Trump wipe oun reti ifọrọwanilẹnuwo lati ọdọ adari fun iwadi pataki yi, Robert Mueller laarin ọse Meji si Meta, pẹlu ifọwọsi awọn agbejọro oun.

Nigba to n sọrọ ni Ile Ijọba Aarẹ Ilẹ Amẹrika, White House, sọ wipe oun ti gbaradi fun ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ibura labẹ olusewadi agba naa.

Ti a ko ba gbagbe, Aarẹ ilẹ Amẹrika, ti o sọ tẹlẹri, wipe oun o ro wipe Mueller le se ifọrọwani lẹnu wọ fun oun, ati wipe oun nigbagbọ pe irọ lasan ni pe Russia nise pẹlu bi ohun se di aarẹ orilẹede Amerika.

Nibayi, ile-isẹ ọtelẹmuyẹ lorilẹede Amerika gbagbọ wipe orilẹede Russia lẹdiapopọ pẹlu awọn olupolongo fun aare Donald Trump nigba ti o dije sipọ aarẹ lọdun 2016. Eleyi ti wọn sọ wipe o se okunfa bi Trump se yege ninu idibo naa.