Saraki wa lara awọn asofin to n gbowo osu lọna meji

Bukọla Saraki, olori ile asofin agba ni Naijiria
Àkọlé àwòrán Ona meji ni Saraki ti n gbowo osu gẹgẹ bi SERAP ti sọ

Ajọ to n ja fun ifẹsẹmulẹ ẹtọ ọmọniyan lẹka ọrọ aje, igbayegbadun wọn ati ijiyin isẹ iriju ẹni (SERAP), ti gba idajọ nile ẹjọ wipe ajọ naa lẹtọ lati pe awọn asofin ati minista kan lẹjo.

Awọn minista ati asofin wonyi jẹ awọn ti wọn ti figba kan ri jẹ gomina tẹ̀lẹ́ri ni ìpinlẹ̀ wọn, ti wọn si n gba owo ifeyinti pelu owo asofin lọ̀wọ̀lọ̀wọ̀.

Adajọ Olurẹmi Oguntoyinbo ti ile ẹjọ giga ti ilu Eko lo se idajọ naa

Siwaju si, SERAP n sọwipe ki wọn da owo to to aadota biliọnu pada si apo ijọba.

Àkọlé àwòrán Akpabio je okan lara awọn gomina tẹlẹri to n gbowo lọna meji

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Oguntoyinbo ni "a ko lee ri ajọ SERAP bii alatojubọ ninu ọrọ yi, bẹẹ si lo lẹtọ lati pe ẹjọ, fi dawọ irufẹ igbese naa duro.

Related Topics