Iba apọ́njú ni Naijiria: Eto abẹrẹ́ yoo bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ni awọn ipinlẹ̀ kan

Abẹ́rẹ n fa oogun àjẹsára ninu igo
Àkọlé àwòrán,

Enìyàn márùndínláàdọ̀ta ló pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àìsàn ibà pọ́nju ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ́dún 2018

Lóní ni eto gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àìsàn ibà apọ́njú (Yellow Fever) yòó bẹ̀rẹ̀ jákè-jádò oríléèdè Naijiria. Mílíọ́nù mẹ́ẹ̀dọ̀gbọ̀n ènìyàn sì ni ìrètí wa pe yòó jẹ àǹfàáni ètò naa.

Ijọba ilẹ̀ Naijiria pẹ̀lú àjọ to n rí sí ètò ìlera lágbáye, WHO to fi mọ́ Unicef ń gbéèro láti sètò náà jákè-jádò oríléèdè Nigeria lọ́dun 2018.

Igbésẹ̀ naa ni yóò jẹ́ èyí tó tóbi jù ti Nigeria tí i gbe.

O jẹ́ ara akitiyan tó ń lọ lágbaye lati fi òpin sí itankalẹ̀ iba pọ́nju naa, ti yoo ba fi di ọdun 2026.

Ipinlẹ̀ Kogi, Kwara ati Zamfara ni eto naa yoo ti bẹ́rẹ́.

Lọ́wọ́-lọ́wọ́, orilẹ̀ede Naijiria n fojuwina aisan naa to ti bẹ̀rẹ̀ lẹ́kùn iwọ̀ oorun nínú oṣù kẹsan, ọdún 2017.

Okodoro nípa ibà apọ́njú

  • O maa ń wọ àgọ́ ara ènìyàn tí ẹ̀fọn tó nìí bá jẹ irú ẹni bẹ̀ ẹ́
  • Awọn àpẹrẹ tí ó màá ń fihàn ni, ibà, orí fífọ́, ara-ríro, èébi, àyà rínrìn àti àárẹ
  • O màá ń ṣekúpa ìlàjì àwọn tó bá nì í làárin ọjọ́ méje sí mẹ́wàá
  • O wọ́pọ̀ nílẹ̀ Afíríkà àti gúsùú Amẹ́ríkà.

Ọ̀nà láti dènà rẹ̀ẹ́

  • Gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára
  • Pípa àyíká ẹni mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fọn
  • Sisun lábẹ́ àpò apẹ̀fọn.

Bíótilẹ̀jẹ́ wípé mílíọ́nù mẹ́ta ènìyàn ló gba abẹ́rẹ́ nàá lópin ọdun 2017, ṣùgbọ̀n èyí kò fi òpin sí itankalẹ̀ arun yi.

Ní ìbẹ́rẹ́ ọdún yìí, ènìyàn márùndínláàdọ̀ta ló pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àrun iba pọ́nju.

Brazil ti kéde ìgbésẹ̀ pàjáwírì

Kò din ní ènìyàn mẹ́ẹ̀dógún tó ti kú l'óríléède Brazil nítori àìsàn yíì, wọ́n si ti kéde ìgbésẹ̀ pàjáwírì lẹ́ka ètò ìlera ní ìpínlẹ̀ Minas Gerais tó wa ní ẹkùn ìlà oorun gúùsù Brazil.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè tó fi mọ́ Belo Horizonte, tíì ṣe olú-ìlú Brazil lọwọ́jà àìsàn náà ti dé.

Etò abẹ́rẹ́ àjẹsára nàá ti bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ìpínlẹ́ mẹ́ta lẹ́kun gúùsù.

Ajọ WHO si ti rọ ẹnikẹ́ni tí yòó ba rin ìrìnàjò lọ sí ìpínlẹ̀ Sao Paulo láti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àìsàn ibà apọ́njú.