Buhari se'pade pẹlu olori ọmọ ogun, alakaso eto aabo

Aarẹ Buhari pẹlu awọn ọmọ igbimọ rẹ kan Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Eto aabo to peye ti jẹ ipenija nla fun orilẹede Naijiria

Aarẹ Muhammadu Buhari ti n ṣe awọn ipade pajawiri nilu Abuja loni latari ipo ati irisi orilẹ ede Naijiria.

Atẹjade kan lori opo ayelujara twita fun ọkan ninu oluranlọwọ fun aarẹ, Bashir Ahmad sọ pe awọn gomina mẹfa se ipade ikọkọ pẹlu aarẹ ni ọjọbọ. Ko sọ ohun ti ipade naa dale lori.

Awọn gomina ti o wa nibẹ ni, Atiku Bagudu ti ipinlẹ Kebbi, Udom Emmanuel lati ipinlẹ Akwa Ibom ati Aminu Masari ti ipinle Katsina.

Awọn ẹlomiran ni awọn gomina Dafidi Umahi ti ipinlẹ Ebonyi, Simon Lalong ti o jẹ gomina ipinlẹ Plateau ati alaga ẹgbẹ awọn gomina orilẹede Naijiria, Abdulaziz Yari ti o jẹ gomina ipinle Zamfara.

Nipa ti awọn Gomina, o tẹ bayi pe:

Ipade lori ọrọ aabo orilẹede.

Atẹjade Basir Ahmad lori ẹrọ Twitta wi bayi pe: