Super Falcons: Thomas Dennerby di olukọni mọọgba

Thomas Dennerby Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Thomas Dennerby yoo dari ikọ ọmọ ẹgbẹ Super Falcons di ọdun 2020

Ile Isẹ igbimọ alakoso fun ere bọọlu orilẹede Naijiria (NFF) ti t'ọwọ b'ọwe pẹlu ogbontarigi akọni mọọgba kan Thomas Dennerby ti o jẹ olukọni agba fun ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu obinrin ti orile-ede Naijiria, Super Falcons.

Olori Ile Isẹ igbimọ alakoso fun ere bọọlu orilẹede Naijiria, (NFF), Amaju Pinnick ti o fi ọrọ yi si ori opo ayelujare Twitta rẹ loni sọ wi pe adehun naa fun Dennerby lati dari awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu obinrin ti orile-ede Naijiria, Super Falcons fun ọdun meji.

Ọgbẹni Pinnick sọ pe Dennerby yoo dari ikọ ọmọ ẹgbẹ Super Falcons di ọdun 2020 pẹlu asọtẹlẹ lori boya yoo gbawe isẹ tan tabi ki o tẹsiwaju gẹgẹbi akọni-mọọgba.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ Super Falcons ti wa laini olukọni fun bii ọdun kan

Dennerby, ti o lo ọdun mẹsan pẹlu Hammarby IF ti Allsvesnkan ti o dẹ gba bọọlu ninu idije fun Ife ẹyẹ ilẹ Yuroopu ni ọdun 1983 ati 1985.

O ṣe akoso Ile-iṣẹ awọn agbabọọlu ọmọbinrin Sweden laarin ọdun 2005 ati 2012.

O tun ṣe alakoso ọdọ-ọdọ fun Dubai FA ti o dẹ tun sisẹ ni awọn orisirisi ipo fun ọmọ ẹgbẹ Hammarby laarin 1993 ati 2001.