Eniyan mọkanla wọ ihamọ lori ọmọogun to sọnu in Adamawa

Ikọ omo ogun orileede Naijiria Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn omo ogun nkoju awon to n dunkoko moni

Alakoso ikọ ọmọ ogun ti ilu Yola (23rd Armoured Brigade) Brig. Gen. Bello Mohammed, sọ pe awọn eniyan afurasi mọkanla ti wa ni ihamọ pe wọn mọ nipa ọmọ ogun orilẹede yi kan ti o sọnu abule Opallo lagbegbe Lamurde ni ipinlẹ Adamawa.

Ogbẹni Mohammed sọ fun awọn onisẹ iroyin ni ọjọbọ n'ilu Yola pe olori ilu kan wa ninu awọn afunrasi yii.

"olori ilu kan, ti a fi orukọ bo lasiri ni a ti tu silẹ lori ìbéèrè ti oloye ti Bachama Chefdom, Honest Irina pẹlu ileri pe oun yoo se awari awọn ti wọn wa nidi isẹlẹ naa", eyi jẹ alaye to se.

Ogbeni Mohammed sọ pe ẹgbẹ ọmọogun kan ti bẹrẹ isẹ iwadi ni agbegbe naa lati wa ọmọ-ogun ti o sọnu yii.

Nibayi, awọn eniyan n saa kuro ni abule Opallo nitori iberu sisọnu ọmọogun yi lee se okunfa ihamọ fun ọpọlọpọ wọn.

Awọn olugbe kan sọ pe awọn apaniyan ti ju ina si apakan ninu abule naa.