SERAP: Owo ifẹyinti ko tọ si ẹni ti o sisẹ gẹgẹ bii gomina

Ipade igbimọ isakoso orilẹede Naijiria Image copyright APC/ Twitter handle
Àkọlé àwòrán Ọpọ awọn gomina nigbakanri lo tu n gba owo osu gẹgẹ bii minisita

Ariwo nla lo sọ kaakiri orilẹede yii ni awọn asiko diẹ sẹyin nigba ti awọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria gbe ofin owo ifẹyinti kalẹ fun awọn gomina ati igbakeji wọn.

Pupọ ninu awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo lọgun sita ti wọn si koro oju si awọn ipinlẹ bii Akwa Ibom, Kwara, Rivers ati ipinlẹ Eko lori igbesọ yii.

Amọsa ohun to tubọ kọ awọn eniyan lominu ko ju bi o se jẹ wipe pupọ ninu awọn gomina ana wọnyii ti wọn se ofin yii gbe lẹyin ni wọn tun fo fẹrẹ gba aga ipo oselu miran lọ bii ile asofin agba, Minisita ati bẹẹbẹẹlọ.

Ofin ifẹyinti fun awọn gominani ipinlẹ Kwara:

 • Ni osu 2010 ni atunyẹwo de ba ofin yii lasiko isejọba Saraki
 • Iye owo osu ti gomina to ba wa lori oye ba n gba ni wọn yoo maa san gẹgẹbii owo ifẹyinti fun awọn gomina tẹlẹ nibẹ
 • Ọkọ ayọkẹlẹ tuntun marun, ninu eyi ti wọn yoo ti maa gbe tuntun meji rọpo fun-un lọdun mẹta-mẹta
 • Ilẹ oni yara marun ti wọn ra ohun gbogbo to tọ si
 • Owọ ọjẹmọnu fun rira ijoko ati ohun elo ile miran. Eyi yoo jẹ ida ọọdunrun owo osu re laarin ọdun meji-meji
 • Awọn osisẹ atọju ile marun ti awọn pẹlu lẹtọ sii owo ifẹyinti
 • Ọlọpa mẹjọ, osisẹ ọtẹlẹmuyẹ SSS mẹta, ti ọkan ninu wọn si gbọdọ jẹ obinrin
 • Eto iwosan ọfẹ fun awọn gomina, igbakeji gomina ati awọn ẹbi i wọn
 • Isinmi ọlọgbẹ ọjọ ni oke okun pẹlu owoona fun gbogbo ọgbọ ọjọ naa
 • Ida ọgbọn ninu ọgọrun owo osu rẹ gẹgẹbii ajẹmọnu owo fun atunse ọkọ
 • Ida ogun ninu ọgọrun owo osu rẹ gẹgẹbii ajẹmọnu owoona atigbadegba
 • Ida mẹwa ninu ọgọrun owo osu rẹ gẹgẹbii ajẹmonu owo igbafẹ
 • Ida mẹwa ninu ọgọrun owo osu rẹ gẹgẹbii ajẹmonu owo itọju ile.

Eyi to jasi wi pe, bi awọn gomina tẹlẹri wọnyii se ngba owo ifẹyinti ni ipinlẹ ti wọn ti se ijọba ri ni wọn tun ngba owo osu lẹnu ipo ilu tabi ipo oselu ti wọn n dimu lọwọlọwọ.

Awọn gomina tẹlẹri ti aje ọrọ yii si mọ lori ni Amofin Raji Fasola to jẹ gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ sugbọn ti o ti di minisita fun ipese ina ọba, ilegbigbe ati akanse isẹ; Rotimi Amaechi to jẹ gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ ti o ti wa di minisita fun igbokegbodo ọkọ.

Image copyright NIGERIA SENATE/TWITTER
Àkọlé àwòrán Awọn gomina nigbakanri ti wọn ti di asofin agba pẹlu n janfani owo ọya meji.

Bakanna ni ọrọ tun kan sẹnatọ Godswill Akpabio toun pẹlu ti figbakanri jẹ gomina ipinlẹ Akwa Ibom ki o to wa di asofin agba bayii ati sẹnatọ Bukọla Saraki ti oun pẹlu ti jẹ gomina ri ni ipinlẹ Kwara ki o to di aarẹ ile-asofin agba orilẹede Naijiria.

Eyi lo sun ajọ kan to nja fẹtọ araalu, SERAP lati gbe amofin agba orilẹede Naijiria lọ si iwaju ileẹjọ nibi ti o ti rọ ileẹjọ lati kan-an ni ipa fun-un pe ko gbe awọn ipinlẹ ti ọrọ kan naa lọ si ileẹjọ lati wọ igi le ofin naa lẹyẹ-o-sọka.

Nibayii ti ileẹjọ ti dajọ wipe ki ajọ naa tẹsiwaju, ati wi pe o lọtọ lati gbe amofin agba lọ sileẹjọ lori ọrọ naa, Ajọ SERAP ni igbesẹ akọkọ leyi ja si lati rii pe awọn oloselu dẹkun rirọ araalu jẹ.

Ofin ifẹyinti fun awọn gominani ipinlẹ Eko:

 • Ida ọgọrun Iye owo osu ti gomina to ba wa lori oye ngba
 • Ọkọ ayọkẹlẹ tuntun mẹfa, lọdun mẹta-mẹta
 • Ọkọ ayọkẹlẹ tuntun marun fun igbakeji gomina, lọdun mẹta-mẹta
 • Ile nla kan nilu Eko, ọkan ni ilu Abuja
 • Ile kan soso ni ilu Eko nikan ni igbakeji gomina yoo lẹtọ si
 • Eto iwosan ọfẹ fun awọn gomina, igbakeji gomina ati awọn ẹbi i wọn titi di ọjọ iku wọn
 • Awọn osisẹ atọju ile marun ti awọn pẹlu lẹtọ sii owo ifẹyinti
 • Owọ ọjẹmọnu fun rira ijoko ati ohun elo ile miran. Eyi yoo jẹ ida ọọdunrun owo osu re laarin ọdun meji-meji
 • Ida mẹwa ninu ọgọrun owo osu rẹ gẹgẹbii ajẹmonu owo itọju ile
 • Ọlọpa mẹjọ, osisẹ ọtẹlẹmuyẹ SSS meji, ti ọkan ninu wọn si gbọdọ jẹ obinrin
 • Igba keji gomina yoo gba Ọlọpa meji, osisẹ ọtẹlẹmuyẹ SSS kan.
 • Ida ọgbọn ninu ọgọrun owo osu rẹ gẹgẹbii ajẹmọnu owo fun atunse ọkọ.
 • Ida mẹwa ninu ọgọrun owo osu rẹ gẹgẹbii ajẹmonu owo igbafẹ
 • Ida ogun ninu ọgọrun owo osu rẹ gẹgẹbii ajẹmọnu owoona atigbadegba
 • Awakọ ti oun pẹlu yoo maa gba owo ifẹyinti.

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, oludari agba fun ajọ SERAP, ọgbẹni Adetokunbo Mumuni titọ ile ẹjọ lọ ni yoo yẹ ọna fun igbẹjọ gan ti yoo waye ni osu kẹta ọdun 2018.

"Pataki idajọ yii ni wi pe a o fi lee mọ boya lootọ ni ijọba to wa lode bayii nfẹ anfani araalu tabi oun pẹlu yoo pẹlu ọbọ jawura nipa kikuna lati fi ọna ofin wa egbo dẹkun si awọn ofin fa-mi-lete-n-tutọ ti awọn adari orilẹede yii kan nlo lati fi rẹ araalu jẹ".

Image copyright NIG. FMW/ twitter
Àkọlé àwòrán Gomina ana ni ipinlẹ Eko, Raji Fasọla n gba owo ifẹyinti leko, o si tun n gba owo osu gẹgẹ bii minisita

Ọgbẹni Mumuni tun salaye wipe asiko to lati pe awọn asiwaju ti ko nifẹ araalu sita wa jihin isẹ iriju ti ilu ran wọn dipo ki wọn maa fi ọwọ ọla gba araalu loju.

"Owo ifẹyinti ko tọ si ẹni ti o sisẹ gẹgẹ bii gomina ilu fun patapata ọdun mẹjọ. A ri i wipe ọpọlọpọ awọn ipinlẹ wsnyii ni wọn jẹ awọn osisẹ lowo osu, ti wọn ko si tun lee san owo ifẹyinti fun awọn to ti fi irun dudu sin ilu ti wọn wa n fi irun funfun jiya. Afi ti ijọba Buhari ati awọn alaranlọwọ rẹ ba ni a ko si ni ijọba awarawa mọ lo ku".