Ile Asofin pasẹ fun NNPC lati dẹkun ọwọngogo epo

Awọn ero to fun epo Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lati osu kejila ọdun 2017 ni orilẹede Naijiria ti n ba isoro ọwọngogo epo finra

Nibayii ti wahala ọwọngogo epo ni orilẹede Naijira n se bi eyi ti ko fẹ gboogun mọ, awọn ile igbimọ asofin agba ni ilẹ Naijiria ti gbe awọn afẹnuko mẹta kan kalẹ gẹgẹ bii ara ọna lati wa ojuutu si foniku-fọla dide wahala epo bẹntiroolu ati eroja rẹ gbogbo.

Nibi ijoko ile to waye ni ọjọọbọ, awọn asofin agba fun ileesẹ ipọnpo rọbi ni ilẹ Naijiria ni gbedeke ọjọ meje lati rii daju pe opin de ba tito gbọọrọ-gbọọrọ lawọn ile ipo eyi ti ko sẹyin ọwọngogo epo bẹntiroolu.

Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Awọn sẹnatọ ilẹ Naijiria ni ajọsepọ gbogbo ẹka to nii se pẹlu ipese epo fun araalu se pataki

Awọn sẹnatọ ilẹ Naijiria ni ọna to ba wu ajọ NNPC ni ko gba, sugbọn ki epo saa ti wa ni arọwọto araalu ni iye owo ti ijọba fi ọwọ si.

Bakanna ni awọn sẹnatọ ọhun tun fi ohun ransẹ si awọn ileesẹ agbofinro gbogbo lorilẹede Naijiria wipe ki wọn wa wọrọkọ fi sada ni kia lati rii pe awọn ẹnu aala orilẹede yii ko jo bi omi inu apọrọ mọ lati lee pin awọn fayawọ ti o n ko epo rọbi kuro ni ilẹ Naijiria lọ ta loke okun lọwọ.

Image copyright @NNPCgroup
Àkọlé àwòrán Ajọ NNPC ni ọjọ meje lati fi wa opin si wahala epo ni ilẹ Naijria

Bakannaa ni ileegbimọ asofin agba naa tun fẹnuko wipe asiko to fun ileesẹ to nse amojuto ẹka epo rọbi nilẹ Naijiria, DPR lati tubọ ta okun amojuto rẹ ko rinlẹ daadaa lati rii daju pe awọn to n ta epo bẹntiroolu ati eroja rẹ gbogbo ko taa kọja iye ti ijọba apapọ fi ọwọ si.

Ninu ọrọ rẹ, aarẹ ileegbimọ asofin agba ilẹ Naijiria ni " ni iwoyi ọsẹ ti o n bọ, igbimọ ile lori ọrọ epo rọbi ni lati jabọ fun ileegbimọ yii wipe ajọ NNPC ti mu ifẹnuko ti ile se yii sẹ. Nitori asiko to lati fi opin si gbogbo gulegule ọwọn gogo epo yii."

Lati osu kejila ọdun 2017 ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti n ba isoro ọwọngogo epo finra eleyi ti ko dopin bi o tilẹ jẹ wipe awọn alasẹ ajọ elepo rọbi ilẹ Naijiria n lọgun pe awọn n ko epo wọ ilu.