Ijọba pasẹ fawọn agbofinro lati tọpinpin ọrọ ikorira lori ikanni ayelujara

oju opo Facebooku lori ẹrọ kọmputer Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọrọ ikorira ti di agbẹdọ ni orilẹede Naijria pẹlu asẹ tuntun lati ọdọ ijọba

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti pa asẹ fun awọn ileesẹ alaabo gbogbo lati ji giri si gbigbogun ti itankalẹ awọn ọrọ ikorira lawọn ikanni ayelujara (social media) gbogbo.

Nibi ipade kan ti aarẹ Muhammadu Buhari se lori ọrọ abo pẹlu awọn lọgalọga ileesẹ alaabo ati ologun lorilẹede Naijiria, eyi to waye nilu Abuja ni asẹ yii ti jade.

Minisita fun eto abo lorilẹede Naijiria, Mansur Dan Ali to salaye ọrọ yii ni, ọwọ ti awọn ọrọ ikorira n ba jade bayii lori awọn ikanni ayelujara (social media) n fẹ amojuto.

"Gbogbo awọn ileesẹ alaabo gbogbo lo ni lati dide ni kia lati koju itankalẹ awọn ọrọ ikorira ikanni ayelujara (social media), paapaajulọ laarin awọn ọtọkulu ọmọ orilẹede Naijiria."

Image copyright Nigeria Defence HQ/ twitter.
Àkọlé àwòrán Awọn osisẹ alaabo ti gba asẹ lati maa tan ina wa ọrọ ikorira lori ikanni ayelujara, social media.

Igbesẹ yii nwaaye lẹyin nkan bii ọdun kan ti minisita feto iroyin, Lai Mohammed ti jẹjẹ wipe ijọba apapọ ko ni da si ohun ti awọn eniyan nsọ lori ikanni ayelujara (social media).

"Ko si nkan to kan ijọba pẹlu ohun to nlọ lori ikanni ayelujara (social media); yala ni isiinyi tabi ni ọjọ iwaju." Ni ọrọ ti Minisita Lai Mohammed sọ ni osu kini ọdun 2017.

Amọsa, minisita feto abo, Dan Ali salaye fawọn akọroyin wipe koko to jẹyọ nibi ipade oniwakati mẹta naa ni awọn ofin massu-maa tọ ti ilẹ Amẹrika gbe kalẹ fun orilẹede Naijiria ki o to lee ta awọn baluu ijagun Super Tucano A29 mejila ati awọn ohun ijagun miran fun ilẹ Naijiria ni miliọnu marundinlẹẹdẹgbẹta dọla, owo ilẹ Amẹrika.

Image copyright 1996 VT Freeze Frame
Àkọlé àwòrán Ọrọ ikorira ti di agbẹdọ ni orilẹede Naijria pẹlu asẹ tuntun lati ọdọ ijọba

O ni, ilẹ Amẹrika ti kan-an ni ọranyan fun ilẹ Naijiria lati san owo naa ki o to di ogunjọ osu keji ọdun 2018, bẹẹni ki o to lee di wipe o tẹwọgba awọn baluu ogun naa, yoo di ọdun 2020, iyẹn ọdun mẹrin si asiko yii.

Bakannaa ni minisita Dan Ali tun sọ wi pe, lara awọn nkan mii ti ilẹ Amẹrika beere fun ni pe ko si aaye funfifi awọn osisẹ omọogun ilẹ Naijira sswọ si ilẹ Amẹrika lati kọ nipa bi wọn se se awọn baluu ogun naa.

O ni ijọba Naijiria nbeere pe bawo ni ọbọ se se ori ti inaki o se niwọn bo se jẹ wipe orilẹede Amẹrika yii kan naa faaye gba awọn osisẹ orilẹede miran to ta awọn baluu yii fun lati wa kọ bi wọn se to awọn baluu naa jọ.

Minisita feto abo ilẹ Naijiria wa fi kun-un pe, igbimọ naa ti fọwọ sii ki awọn osisẹ ileesẹ eto abo nijọba apapọ o lọ fikuluku pẹlu asoju ijọba ilẹ Amẹrika ni ilẹ Naijiria, ọgbẹni Stuart Syminton lati yannana ọrọ naa.