Ethiopia kede ilu o fararọ

Awọn oluwọde ni Ethiopia

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Ogunlọgọ oluwọde lo n tako ijọba to wa lode ni Ethiopia

Ethiopia ti kede pe orilẹede naa ko fararọ lẹyin ọjọ kan pere ti olootu ijọba orilẹede naa kọwe fipo rẹ silẹ.

Atẹjade kan ti ijọba orilẹede Ethiopia fisita ni igbesẹ yi pọn dandan lati mu adinku ba oniruuru iwa ifẹhonuhan to n waye lorilẹede naa.

Ogunlọgọ awọn eeyan Ethiopia lo ti jalaisi latipasẹ aifararọ to n waye lorilẹede naa lati ọdun mẹta sẹyin.

Ikede ilu ko fararọ olosu mẹwa to waye lọdun to kọja kuna lati fopin si iwọde naa, gẹgẹ bi itusilẹ ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọ ẹgbẹ alatako to wa lahamọ ti kuna lati f'opin si iwọde naa.

Wọn ko sọ gbedeke akoko ti ikede ilu ko fararọ naa yoo lo tabi awọn ilana tawọn araalu gbọdọ tẹle lori rẹ.