APC fun ijọba ipinlẹ lagbara fun isakoso ohun alumọọni

Gomina El-Rufai ati Odigie Oyegun Image copyright @elrufai
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ APC n tiraka lati se atunto Naijiria

Igbimọ to wa fun agbeyewo ilana aparo kan ko ga ju ọkan lọ ati agbeyẹwo ilẹ Naijiria, ti ẹgbẹ oselu APC gbe kalẹ, eyiti Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai ko sodi ti gbe abọ iwadi rẹ kalẹ.

Abọ̀ iwadii naa daba onikoko mẹwa eyi to da lori igbesẹ pinpin ipo agbara fawọn ijọba ipinlẹ, lọna ati se atunto ilẹ Naijiria.

Lara awọn ohun ti igbimọ naa daba ni ominira nla fawọn ijọba ipinlẹ, nipa gbigbe awọn ofin kan kuro labẹ isọri ofin ti ko wa fun gbogbo-gboo, lọ sabẹ awsn ofin to wa fun lilo lati igbadegba.

Ijọba ipinlẹ ni yoo maa s'akoso ohun alumọọni

"Ọrọ awọn osisẹ to fi mọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ olokoowo, ibasepọ laarin awọn osisẹ ati agbanisisẹ, ilana isọwọsisẹ, aabo lẹnu isẹ ati eto idẹrun osisẹ to fi mọ yiyanju aawọ, ati agbekalẹ ilana owo osu to kere julọ ati yiyanju aawọ osisẹ ati awọn agbanisisẹ lo yẹ ko wa labẹ awọn ofin atigbadegba".

Lẹyin agbekalẹ abọ igbimọ naa, ni alaga ẹgbẹ APC, Oloye Oyegun wa ki wọn ku isẹ takuntakun ti wọn se, to si kede pe pẹlu igbesẹ yi, gbogbo aye ti wa mọ ohun ti ẹgbẹ oselu APC duro fun.

Alaga igbimọ agbeyẹwo eto atunto ilẹ Naijiria naa, El-Rufai, lasiko to n gbe aba naa kalẹ fun alaga igbimọ amusẹya fẹgbẹ oselu APC nilẹ yi, John Odigie-Oyegun, nibi ayẹyẹ kan nilu Abuja ni ero igbimọ naa ni pe kawọn ọrọ to nii se pẹlu oogun oloro ati ọpọlọ si duro labẹ ofin ti ko si fun gbogbo-gbo.

Sugbọn awọn ohun to nii se pẹlu ounjẹ, oogun ati majele wa labẹ awọn ofin atigbadegba, ko baa lee rọrun fawọn ijọba ipinlẹ lati gbe ofin kalẹ lori wọn.

Ohun to tun sikẹta ninu awọn aba gbigbe awọn ofin kan lọ sabẹ isọri ofin atigbadegba ni ọrọ to nii se pẹlu awọn osisẹ, ti El-Rufai si kede pe eyi yoo mu ko rọrun fun ijọba apapọ atawọn ipinlẹ lati se ofin lelori.

Awọn koko aba mii ti ẹgbẹ APC gbe kalẹ:

Image copyright APC
  • Ipinlẹ kọọkan ni yoo maa san iye owo osu ti agbara rẹ ba ka fawọn osisẹ rẹ
  • Gbogbo awọn ohun alumọọni bii epo rọbi ati afẹfẹ gaasi, iwakusa, kanga epo ati agbeyẹwo ayika fun awari ohun alumọọni, ni yoo jẹ ojuse awọn ijọba ipinlẹ bayi
  • Awọn ijọba ipinlẹ yoo ni ileesẹ ọlọpa tiwọn labẹ ofin idasilẹ wọn ti yoo di ofin atigbadegba
  • Eto akoso ọgba ẹwọn naa yoo di ẹru awọn ijọba ipinlẹ
  • Ofin idasilẹ ileesẹ nilẹ yi naa yoo wa labẹ ofin atigbadegba kawọn ipinlẹ lee maa gba owo ori ọja labẹle
  • Awọn ọmọ ipinlẹ mii to ba n gbe nipinlẹ ti kii se tiwọn lee di ọmọ ipinlẹ naa
  • Oludije to da duro yoo wa lati kopa ninu idibo laisi ninu ẹgbẹ oselu kankan.