Trump:Ẹ forijinmi lori atuntẹ twita mi

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump Image copyright Donald Trump/Twitter
Àkọlé àwòrán Ẹ ma binu gbe mo se atuntẹ aworan naa

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti tọrọ aforijin fun igba akọkọ lori bo se se atuntẹ fọnran aworan kan tawọn igun kan nilẹ Gẹẹsi gbe sori opo Twitter, eyi to n safihan iwa ipa awọn ẹlẹsin Islam, ti wọn se afihan rẹ lori tẹlifisan ITV nilẹ Gẹẹsi lọjọ ẹti.

"Tẹẹ ba ni awọn ẹlẹyamẹya to buru pupọ lawọn to gbe fọnran aworan naa jade, mo setan lati tọrọ aforijin toba wu yin ki n se bẹẹ."

Donald Trump kede ọrọ yi fun Piers Morgan lori eto redio kan ti wọn pe ni 'Good Morning Britain' nibi to ti n seto ifọrọwanilẹnuwo pẹlu rẹ nilu Davos lana ọjọbọ.

Related Topics