Arun Iba ọrere: Awọn alasẹ gbọdọ gba itọju nilẹ yi

Ile iwosan ijoba apapo nilu Abuja Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Aabo to peye yẹ ko wa fawọn olutoju alaisan lọwọ ajakalẹ arun.

Onisegun Oyinbo kan Dokita Kunle Obilade ti kede pe nibi taa ba ti n wo olokunrun, laa ti n wo ara ẹni, nitori naa, yoo dara kijọba ilẹ wa maa pese ohun eelo aabo to yẹ fawọn olutọju alaisan nile iwosan.

O fikun pe yoo daa kawọn naa si dẹkun lilọ gba itọju loke okun, ki wọ̀n baa le raye gbọ bukata to yẹ lori awọn ile iwosan to wa nilẹ yi, paapa lasiko ti ajakalẹ arun ba bẹ silẹ, kawọn olutọju alaisan aa ba lugbadi arun naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAabo to peye gbọdọ wa fawọn olutọju alaisan

Lasiko to n sedaro awọn dokita mẹrin to ku nigbati wọn n setọju awọn alarun iba ọrẹrẹ, nipinlẹ Ebonyi ati Kogi ni o se ni laanu pe ọpọ igba lawọn olutọju alaisan maa n se agbako iku ojiji lẹnu isẹ wọn, paapa lasiko ti ajakalẹ arun ba bẹ silẹ, eyi to ni ko yẹ ko ri bẹẹ, nitori irufẹ isẹlẹ yi kii saba waye lawọn orilẹede to ti goke agba.

Ijọba gbọdọ setọju awọn ile iwosan wa gbogbo

"Gbogbo ẹbi isẹlẹ yi kii se tawọn olutọju alaisan to ko arun abaadi yi, tabi pe wọn ko mọ isẹ wọn nisẹ ni. Amọ ọpọ ẹbi yi lo wa lọwọ awọn ijọba ni ẹlẹkajẹka nitori bi wọn kii se bikita nipa aabo awọn olutọju alaisan, ti eroja isẹ to peye lati daabo bo wa, ko si si lọpọ ilewosan lorilẹede yi."

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn olutọju alaisan gbọdọ daabo bo ara wọn

Bẹẹ ba gbagbe, dokita onisegunoyinbo mẹrin lo padanu ẹmi wọn ninu osu kinni ọdun 2018 nipinlẹ Ebonyi ati Kogi lasiko ti wọn n setọju awọn eeyan to ni arun iba ọrẹrẹ, taa mọ si Lassa Fever.