OSIEC: Eto ti to fun idibo ijọba ibilẹ

Ọdún 2007 ni ètò ìdìbò sí ìjọba ìbílẹ̀ ti wáyé kẹ́hiǹ ní ìpínlẹ́ Ọ̀ṣun Image copyright State of Osun/Website
Àkọlé àwòrán Ọdún 2007 ni ètò ìdìbò sí ìjọba ìbílẹ̀ ti wáyé kẹ́hiǹ ní ìpínlẹ́ Ọ̀ṣun

Ọjọ abamẹta, iyẹn ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, oṣu kinni ni eto idibò si àwọn ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Ọṣun yoo waye. Ọdun 2007 ni iru eto idibo bẹẹ ti waye gbẹyin.

Eto idibo yii lo sokunfaa bigomina Rauf Arẹgbẹsọla ṣe kede isinmi isinmi lẹnu ise lọjọ kẹẹdọgbọn ati ikẹrindinlọgbọn, ọdun 2018 lati lee fun awọn eeyan ipinlẹ naa laaye igbaradi fun un.

Bi o ti lẹ jẹ wi pe awọn onimọ nipaeto ọrọ aje ni irufẹ ofin bẹẹ ko tọna fun igbeka ọrọ aje.

Wọọdu mọkanlelaadọrin ni idibo yoo ti waye ninu ọọdunrun o le mọkandinlaadọ̀rin to wa ni ipinlẹ̀ naa, eyi ko yẹ lori bi awọn oludije fun idibo lawọn wọọ bii okoo le lọọdunrun ati mejise wọle lai latako.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọjọ abamẹta, iyẹn ọjọ́ kẹrindinlọgbọn, oṣu kinni ni eto idibò si àwọn ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Ọṣun yoo waye

Abala ikọkanlelogoji iwe ofin eto idibo ọdun 2010 fi aaye gba ajọ eleto idibo lati kede awọn oludije ni iru ipo bẹẹ, saaju ni ẹgbẹ oselu PDP ti ni oun ko ni kopa ninu idibo naa.

Ẹgbẹ oselu PDP se apejuwe idibo naa gẹgẹ bi eyi to tako ofin.; to si pe ẹjọ sile ẹjọ giga apapọ nilu Abuja pe ki o da ajẹ eleto idibo ipinlẹ Ọsun lọwọ kọ lori titẹsiwaju pẹlu idibo naa.

Alukoro fuń ajọ OSIEC, Tunde Fanawọpọ ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ ni "ilé ẹjọ ti fun ajọ OSIEC ni aṣẹ lati tẹsiwaju pẹlu eto idibo naa. Ati wipe igbẹjọ yoo waye ni ọjọ kẹtala, oṣu kẹta 2018 lori ẹjọ ti PDP pe."

Ẹ̀wẹ̀, o ni ẹgbẹ oṣelu mẹfa ni yoo kopa ninu eto idibo naa."Awọn ẹgbẹ oṣelu naa ni APC, Accord, Labour, SDP, ACPN ati ADP.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú Tunde Fánawọ́pọ̀, alukoro OSIEC

Lori ipese eto abo lasiko ibo naa, alukoro fun ileesẹ ọlọpa ni ipinlẹ Ọsun, Fọlasade Odoro "gbogbo eto ti wa ni ṣẹpẹ lati ri i pe eto idibo naa lọ ni irọwọ-irọsẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOohun alukoro iléèṣẹ́ ọlọ́ọ́pá ìpìnlẹ̀ Ọ̀ṣun lori ètò ìdìbò