Afurasi ọmọ ẹgbẹ Boko Haram lọwọ ti te ni ilẹ Germany

Aworan awọn ti ologun gbala lọwọ Boko Haram losu kini ọdun yi ni Monguno Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Boko Haram ti jin ogunlọgo ẹniyan gbe lati ọdun 2009

Páńpẹ́ ọba ti mú ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n afurasí Boko Haram kan tó tun jẹ́ ọmọ Naijiria ni orilẹ́ede Germany.

Wọ́n fura sí arákùnrin yìí pé ó wà lára ẹgbẹ́ adúnkokò mọ́ni, Boko Haram tó ń pànìyàn lorílẹ̀ède Nàìjíríà lákòókò àwọn ìkọlù to ń waye ní àwọn ilé ìwe àti ìlú.

Nínú ọ̀rọ̀ olupẹ̀jọ́ ijọ̀ba,ni ọjọru ọ̀sẹ̀ yii won fi arakunrin naa ti orukọ rẹ̀ njẹ́ Amaechi Fred O si atimole lodo awon olopaa ni ilu Bavaria.

Nigba ti o di ojo keji, adajọ́ fi iwe asẹ sita pe ki wọ́n tunbo je ki o rookun latimọ́le.

Wọ́n diidi fura si i pe o jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ adunkokomọ́ni, Boko Haram.

Ohun ti wọ́n ko jọ ni pé Amaechi dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Boko Haram ni ọdun 2013.

Wọn lo kopa ninu ikolu ile iwe ati ijinigbe

O jewo wipẹ ọun kopa ninu ikolu mẹrin laarin ọdun kan to fi jẹ ọmọ ẹgbẹ naa.

Wọ́n fẹ̀sun kan an wipe o ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ eniyan lakoko ikọlu meji ni awọn ile iwe, ikọlu kan si ilu kan ati omiran si ilu mii ninu eyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram ti ko awọn ọmọbinrin nigbekun ti wọn si fi ina si ile ijọsin kan.

Lati ọdun 2009 ni ẹgbẹ́ BokoHaram ti ngbiyanju lati se agbekalẹ ijoba tara won ni ẹkun ila oorun-ariwa Naijiria labe esin Islam.

Lati ibe ni wọ́n ti se ifilọ́ọ́lẹ̀ ọsẹ́ sise to fi mọ́ jiju ado oloro ni orilẹ̀ede Niger, Chad ati Cameroon.

O ti le ni ẹgbẹ̀run mẹ́ẹ̀dọ́gọbọ̀n eniyan ti wọ́n ti pa.

Ọ́pọ̀lọ̀pọ̀ miliọ̀nu ni wọ́n ti sọ di alairilegbe.