Idibo ijọba Ibilẹ n waye nipinlẹ Ọsun

Awon oludibo nibi eto ibo Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ awọn ti o n dibo ni ipinlẹ Osun jẹ awọn agbalagba

Orisirisi iroyin lo ti n tẹ wa lọwọ lori bi n kan se n lọ ninu idibo ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Osun ti o n waye loni jakejado ipinlẹ naa.

Ajọ eleto idibo ipinlẹ Osun (OSIEC), nigba ti wọn n ba ile isẹ BBC sọrọ sọ pe, ko si konu-n-kọhọ kankan nitori pe eto idibo ọhun n lọ ni irọwọrọsẹ. Alaga ajọ eleto idibo ni ipinlẹ Ọsun, ọgbẹni Sẹgun Ọladitan sọ pe, ko si wahala kankan ati pe awọn eniyan jade lọpọ yanturu lati dibo ti awọn osisẹ alaabo naa si wa ni sẹpẹ.

Sugbọn, ẹni ti o jẹ alaga ẹgbẹ Accord ni ipinlẹ Osun, Ọgbẹni Olusegun Ayọdele sọ pe orisirisi awọn oun aitọ lo waye ninu idibo ọun. O sọ pe ni agbegbe Modakẹkẹ ati Ifẹ paapaa julọ, nibi ti ẹgbẹ Accord ti dije idibo, o ni ọpọ idun mahuru-mahuru lo waye pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ naa.

O salaye pe nise ni awọn osisẹ ajọ eleto idibo ko tete ko awọn ohun idibo de awọn wọọdu kan, ti o si jẹ pe awọn janduku ji iwe idibo ko lawọn agbegbe miran. O tun sọ siwaju pe ọpọ awọn agbegbe ni o jẹ pe awọn ara ilu ko jade wa dibo rara nitori ibẹru-bojo fun aabo ẹmi wọn.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Eto idibo lati yan awọn oludari ati ẹmẹwa wọn n waye fun awọn ijọba ibilẹ ọgbọn nipinlẹ naa.

Nigba ti ile isẹ BBC ba Komisọna ọlọpa ni ipinlẹ Osun, Ọgbẹni Fimihan Adeoye sọrọ, o ni ko si wahala kankan ni awọn ibudo idibo, pe eto aabo wa ni sẹpẹ kaakiri ipinlẹ ọsun fun awọn oludibo ati awọn osisẹ ajọ eleto idibo.

Ninu iroyin to tẹ wa lọwọ, wọọdu mọkanlelaadọrin ni eto idibo ọun ti n waye ninu ọọdunrun le mọkandinlaadọrun wọọdu to wa ni ipinlẹ Osun.

Idi ti eto ko fi waye lawọn wọọdu kan ni pe ẹgbẹ APC ko ni alatako kankan nibẹ̀.