Dino Melaye: Ki lo tun ku ti o sọ?

Asofin Dino Melaye Image copyright @dinomelaye
Àkọlé àwòrán Asofin Melaye ti figba kan korin 'Ajekun Iya' si awọn alatako rẹ ni ọdun 2017.

Ọmọ ile igbimọ asofin, Dino Melaye, ti fi fidio miran sita ninu eyi ti o ti sọrọ, kọrin eebu si Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello.

Asofin melaye fi fidio yi sori opo ayelujara instagramu rẹ lọjọ ẹti.

Agbẹnusọ rẹ kan, Gideon Ayọdele fidi rẹ mulẹ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo wipe Asofin Melaye funra rẹ lo fi fidio naa sori opo rẹ.

Ninu fidio ti a fi sori ẹrọ Instagramu yi, Melaye sọ pe oun la ala kan nibi ti oun ti ri Ogbẹni Bello ninu "asọ ẹwọn pẹlu ẹṣọ pataki".

Image copyright @dinomelaye

Ni apakan, Melaye kọrin ni ede Yorùbá pe: Kilo tun ku ti o sọ? Kilo tun ku ti o sọ? Ẹni ti a bẹ lori to n sẹnu wuyẹ, kilo tun ku ti o sọ?

Ẹ ranti wi pe Asofin Melaye ti figba kan kọrin 'Ajẹkun Iya' si awọn alatako rẹ ni ọdun 2017.

Ijọba ipinlẹ Kogi ko tii fun un ni esi ọrọ. Igbiyanju BBC lati gbọ ọrọ lati ẹnu Gomina ipinlẹ Kogi ja si pabo. Awọn ẹrọ ibanisọrọ awọn agbẹnusọ gomina wa ni pipa.