Ibalopọ lati ri ojurere lọdọ awọn okunrin je idojukọ nla fun awọn agbabọọlu Super Falcons

Ikọ agbabọọlu Falcon Image copyright ANDY CLARK/AFP/GETTY
Àkọlé àwòrán Ohun oju awọn obinrin agbabọọlu nri lọdọ awọn ọkunrin kii se die

Arabinrin agbabọọlu orilẹede Naijiria tẹlẹri kan (ko fẹ ka da orukọ rẹ) sọ fun ile isẹ iroyin BBC wipe ọrọ fifi ilọkulọ ibalopọ lọ ni ati awọn elere ori ọdan orilẹede Naijiria tẹle 'ra wọn bii satide ati sunde ni.

Arabinrin yii to gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu obinrin agba ti orilẹede Naijiria - Super Falcons ri sọ wipe bi o tilẹ jẹ pe awọn obinrin njiya, awọn onisẹ iroyin Naijiria ko se agbejade to tọ nipa fifi ilọkulọ ibalopọ lọ awọn agbabọọlu obinrin.

Lọsẹ yii ni ile ẹjọ kan ni orilẹede Amerika dajọ ẹwọn ọdun marun-le-laadọsan fun dokita ikọ agbabọọlu USA Olympic tẹlẹ ri, Larry Nassar latari pe o fi ilọkulọ ibalopọ lọ ọpọlọpọ obinrin elere ori papa.

Image copyright SCOTT OLSON/GETTY
Àkọlé àwòrán Dokita yii fi ilọkulọ lọ awọn obinrin elere ori papa ni Amerika

Awọn eniyan kan sara si idajọ yii dara dara nitori o jẹ ajaye lori ẹjọ yii to ti ko ba nkan bii ọdọmọbinrin mẹrin-din lọgọjọ lorilẹede Amerika.

Ko wọ pọ lati ri iru isẹlẹ bayii ninu ere ori papa lorilẹede Naijiria, awọn eniyan kan tilẹ wipe o jẹ iyalẹnu nitori ọpọlọpọ obinrin to n figa gbaga ninu oniruuru idije ori papa.

Fifi ilọkulọ lọ awọn obinrin elere ori papa ti wa tipẹ

Ile isẹ iroyin BBC ba obinrin oniroyin kan sọrọ (ko fẹka da orukọ rẹ), o ni ootọ ni pe wọn nfi ilọkulọ lọ awọn obinrin daa daa ni Naijiria nitoripe oun gaan funra rẹ ti gbọ ọ o si ti sẹlẹ si i ri.

O ni: "osisẹ agba ere ori papa kan lorilẹede Naijiria sọ fun mi pe bi mo ba wa si hotẹẹli oun ti mo si mu 'nu oun dun, yoo fun mi ni iroyin pataki ti mo le gbe jade lori afẹfẹ".

O fi kun un wipe, "Nigba ti mo ni ngo se, o kọ ko fẹ gbọ, o le mi tiiti lori ẹrọ ibanisọrọ pe ki ngba f'oun sugbọn mo pada yọ nọmba rẹ kuro lori ẹrọ ibanisọrọ mi ni".

Ẹwẹ, o sọ pe kii se wipe awọn oniroyin ko fẹ gbe iru isẹlẹ bayii sori afẹfẹ sugbọn ko ya awọn obinrin to ni iriri yii gaan lori lati sọrọ.

Image copyright PIUS UTOMI EKPEI
Àkọlé àwòrán Pẹlu ọpọlọpọ ife ẹyẹ ti wọn ti gba, oju wọn si nri mabo

Eyi jẹ ohun kan ti osisẹ ẹka iroyin fun awọn agbabọọlu obinrin Port Harcourt, Rivers Angels naa gba wipe kii se pe awọn oniroyin ko fẹ safihan iru isẹlẹ bayii. O sọ pe "mo mọ ọpọlọpọ obinrin paapaa ninu ere bọọlu to nfoju ri ilọkulọ ibalopọ sugbọn wọn o le sọ nitori ẹru nba wọn. Awọn akọnimọọgba yoo ti fa wọn leti wipe bi wọn ba fọhun, isẹ wọn tan".

O tun sọ pe koda bi obinrin ti wọn fi ilọkulọ lọ ọhun ba kuro to lọ dara pọ mọ ẹgbẹ mii, wọn a tun pe oludari ẹgbẹ to lọ dara pọ mọ lati taa lolobo ki wọn le pawọpọ foju rẹ han mabo. Awọn akọnimọọgba yii mọ ara wọn, padi-padi ni wọn. Nitori naa, nnkan mba awọn obinrin finra labẹ asọ sugbọn wọn nbu ẹrin kẹẹ soju bii pe ko si nkankan ni".

Amadi sọ pe "bi a ba ni ofin, a o da abo bo awọn to nfara gba isẹlẹ yii ki wọn le sọrọ lai foya pe ẹnikẹni yoo pa wọn lara nitori ẹni to nfi ilọkulọ lọ wọn le lagbara ju wọn lọ. Pẹlu eyi, o da mi loju pe awọn obinrin yoo le jade lati fi ẹsun ilọkulọ ibalopọ sun"

Ọna abayọ si fifi ilọkulọ lọ awọn obinrin elere ori papa

Alatẹjade lori ẹrọ ayelujara nipa ere bọọlu lorilẹede Naijiria, China Acheru sọ fun akọroyin BBC, Busayọ Iruemiobe wipe oun gbagbọ wipe iru ayipada to nsẹlẹ loke okun yii ma nira lorilẹede Naijiria nitori asa wa ati igbe aye wa ti fi awọn ọkunrin si ipo akọkọ ti wọn si le se ohun to wu wọn sugbọn awọn obinrin, ẹyin ni wọn wa.

Ni Naijiria, ọkunrin lo nse eto akoso ju. Awọn ni alasẹ ere bọọlu, akọnimọọgba ati oluranlọwọ akọnimọọgba, bẹẹ si ni awọn ọkunrin lo nha mọ awọn obinrin ju fun ibalopọ.

Nitori naa ni Amadi se mu ọkan le wipe ọna abayọ kan ni lati jẹ ki awọn akọsẹmọsẹ obinrin pọ lara awọn to nsakoso awọn ikọ elere ori papa bii ti adari ikọ agbabọọlu obinrin ilu Port Harcourt to jẹ obinrin to si nja fun ẹtọ awọn agbabọọlu rẹ.