Iheanacho jẹ ami ayo fun Leicester City lẹẹmeji

Ẹgbẹ agbabọọLeicester Image copyright @LCFC
Àkọlé àwòrán Leicester City f'agba han Peterborough

Afẹsẹdara lori ọdan agbabọọlu nni, Fousseni Diabate ati ọmọ Naijiria, Kelechi Iheanacho ti jẹ ami ayo lẹẹmeji gẹgẹ bi ẹgbẹ agbabọọlu Leicester City se fagba han Peterborough pẹlu ami ayo marun si ẹyọkan ninu idije liigi ti wọn sẹsẹ gba tan.

Pẹlu ifẹsẹwọnsẹ yii, ẹgbẹ agbabọọlu Leicester City ti mori ja idije liigi ti wọn gba tan lati dije fun ife ẹyẹ FA.

Bi Fousseni se gbe e to bẹrẹ si ni sun bọọlu naa siwaju ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ni Iheanacho naa gbẹsẹ wọle ti ẹgbẹ agbabọọlu Leicester City si gbaa yọri jalẹ.

Nigbẹyin gbẹyin, ami ayo marun si ẹyọkan ni Leicester City fi fi ẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Peterborough lelẹ.