Aarẹ Rwanda, Paul Kagame gba eku ida adari ajọ AU

Awọn adari ilẹ Afrika nibi ipade apero ajọ AU Image copyright @channelstv
Àkọlé àwòrán Aarẹ orilẹede Congo, Alpha Conde ti gbe eku ida isejọba ni ajọ AU fun aarẹ Rwanda, Paul Kagame

Ni bayii, omi tuntun ti ru, ẹja tuntun si ti wọ 'nu ẹ ninu ajọ isọkan awọn orilẹede Afrika gẹgẹ bi wọn se yan aarẹ Paul Kagame ti orilẹede Rwanda si ipo alaga ajọ naa. Aarẹ Alpha Conde ti orilẹede Congo lo ti wa ni ipo yii tẹlẹ.

Aarẹ Kagame pe fun irẹpọ laarin awọn orilẹede ọmọ ẹgbẹ lati le se aseye ti alakan n s'epo nipa atunto ninu ajọ AU ati ni awọn orilẹede to parapọ di ajọ yii.

Nibi ipade apero naa ẹwẹ, aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti se ifilọọlẹ akanse koko ọrọ lori didoju ija kọ iwa jẹgudujẹra.

Ayẹyẹ iside ipade apapọ ajọ isọkan orilẹede nilẹ Afrika, AU to waye loni waye nilu Addis Abba, olu ilu orilẹede Ethiopia.

Saaju asiko yii, aarẹ Muhammadu Buhari ti kọkọ darapọ mọ awọn akẹgbẹ rẹ lọjọ ẹti to kọja fun eto ifarakinra saaju iside ipade naa. Ọjọ mẹrin si ni aarẹ Buhari yoo lo lorilẹede Ethiopia, ko to pada wale.

Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari tako iwa ajẹbanu, iwa ibajẹ ati asa sise atipo laarin awọn adulawọ

Buhari rọ awọn asaaju Afrika lati yee fi owo fa oju awọn agbebọn mọra

Ninu ọrọ rẹ nibi eto ifarakinra ọhun, Aare Buhari gba awọn olori orilẹede nilẹ Afrika nimọran lati ma se ba awọn janduku ati agbesunmọmi to jẹ pe isẹ wọn ni lati maa domi alaafia ilu ru dunadura, tabi ki wọn maa fi owo fa oju wọn mọra.

Aarẹ Buhari tun fi ero rẹ han lori awọn ọrọ mii bi ọrọ awọn atipo abẹle, iwa ajẹbanu ati igbogun ti iwa ibajẹ kaakiri nilẹ Afrika, ati awọn ọrọ mii to se pataki.

Related Topics